Awọn tọọgi ṣa awọn alatilẹyin Ọla Motunrayọ Oluṣọla yannayanna ni Aboru - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 23 October 2026

Awọn tọọgi ṣa awọn alatilẹyin Ọla Motunrayọ Oluṣọla yannayanna ni Aboru

 -Bẹẹ ni wọn tun gba foonu wọn

Ṣe lọrọ di boo-lọ-ko-ya- fun-mi lagbege kan ni Aboru, Alimọṣọ, nipinlẹ Eko, nigba tawọn afurasi tọọgi ṣadeede yabo ibi tawọn ọmọlẹyin Ọnarebu Ọla Moturayọ Oluṣọla tọpọ mọ si Arikẹ Ayekootọ,ti wọn ṣi sa wọn yannayanna, ti wọn tun gba foonu wọn.ẹ́

Awọn alatilẹyin obinrin naa to n dije fun aṣoju-ṣofin fun agbegbe Alimọṣọ, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, la gbọ pe wọn ṣe ipade lọwọ lakooko tawọn tọọgi yii doju ija kp wọn.

Lara awọn ti wọn faragba ninu iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi iwadii wa ni Peter Martins, ẹni ti wọn dana iya fun ti wọn si gba foonu ẹ mejeeji lọ. Kenneth Nwaeze naa fori ko nibẹ ti wọn tun gba foonu ẹ.

Awọn yooku tun ni Emmanuel Onu ti wọn fi igo kọla fun un. Wọn ni wọn gba foonu Bọsẹ Oni pẹlu ẹgbẹrun mẹfa naira ti wọn ba lọwọ ẹ.

 Bunmi Babalọla, ẹbi Akinsanya ti wọn lo agbegbe wọn fun ipade naa ṣe kongẹ iya yii ti wọn tun gba foonu lọwọ wọn.

Bo tilẹ jẹ pe titi di akoko taa n ko iroyin jọ, a ko le sọ pato nnkan to da wahala silẹ, eyi ti ikọlu yii fi waye.

Ikọlu to waye yii si ti fẹẹ ma mu ifoya bawọn araalu, eyi ti wọn sọ pe o ṣee ṣe ki abo to peye maa wa fawọn alatilẹyin oloṣelu.

Wọn ọrọ naa si fẹẹ dabi ẹni pe wọn ko fẹẹ fawọn araalu gẹgẹ bi ọmọ orileede lanfaani lati ma kopa ninu ijọba dẹmokireesi.

Gẹgẹ bi eto idibo fọdun 2027, ṣe n wọle bọ, wọn ti wa gba awọn eeyan agbegbe Alimọṣọ nimọran lati sa fun gbogbo nnkan to le da alaafia ru, ki wọn si gba ifẹ ati iṣọkan laaye.

No comments:

Post a Comment

Pages