Alaaji Yusuf Ọlanrewaju to jẹ alakoso ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ogun lo mu idaniloju yii lakooko ti wọn ṣe ipade, eyi to waye lọjọruu,Wẹsidee, ọjọ Kọkanlelogun, oṣu yii ni oluule ẹgbẹ wọn to wa ni Onigbongbo, Ọrẹgun, niluu Eko.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o loun ṣakiyesi pe iṣọkan, ifarsjin, ikora ẹni ni janu wa laarin wọn, o wa rọ awọn alakoso ti wọn wa labẹ awọn igberiko ki wọn tan imọlẹ irufẹ bẹẹ sawọn eeyan wọn.
Ọlanrewaju tun fikun ọrọ ẹ pe iṣẹ takuntskun ti ẹgbẹ ọhun ṣe fun ipadabọ aarẹ Tinubu lẹẹkeji gbọdọ tẹsiwaju laisinmi tabi kaarẹ rara ki wọn si
rii pe wọn jẹ ko gbooro kaakiri ipinlẹ Eko.
O tun sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ yii lati jọ forikori lati wa ọna bi tan imọlẹ kiko awọn eeyan jọ yii de ọdọ awọn ọdọ, akẹkọọ atawọn to wa ni agbegbe igberiko.
Gẹgẹ bi abajade ipade wọn, wọn fẹnuko pe gbogbo wọn gbọdọ jọ wa niṣọkan,ki wọn si jọ ṣiṣẹ pọ ni eyi ti yoo mu erongba wọn ṣẹ.
No comments:
Post a Comment