Eyi lohun ti ijọba fẹẹ ṣe fawọn ileetura atawọn ile ijo alaalẹ ni Ipinlẹ Ọyọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 23 September 2026

Eyi lohun ti ijọba fẹẹ ṣe fawọn ileetura atawọn ile ijo alaalẹ ni Ipinlẹ Ọyọ


Ọlawale Ajao, Ibadan

Lati inu Oṣu Kẹwaa, Ọdun 2026 yii lọ, gbogbo awọn ibudo ariya alaalẹ to wa n'Ibadan ati kaakiri ipinlẹ Ọyọ, pẹlu awọn ileetura, titi dori awọn ile ounjẹ ni ipinlẹ naa ni ijọba yoo maa doju ija kọ, iyẹn bi wọn ba kọ lati maa san owo ori sinu apo ijọba ipinlẹ naa.


Kọmiṣanna fun ọrọ Aṣa ati Irinajo Afẹ ni ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Wasiu Ọlatunbọsun, lo sọrọ yii nileeṣẹ ijọba n'Ibadan, nibi apero ọlọjọ meji to waye laarin ijọba pẹlu awọn oludasilẹ ileetura ati ibudo igbafẹ ni ipinlẹ naa, eyi to pari lỌjọruu, Wẹsidee, Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹsan-an, Ọdun 2026 yii.

Bo tilẹ jẹ pe lati ọdun 2021 ni wọn ti ṣagbekalẹ 
ofin owo ori sisan fawọn ileetura, ibudo ariya, ile ounjẹ ati bẹẹ, bẹẹ lọ, Ọmọwe Ọlatunbọsun sọ pe ọpọ ninu awọn ti ọrọ kan ko forukọ silẹ ni ibamu pẹlu agbekalẹ eto ijọba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Afojusun ijọba ni lati jẹ ki awọn ti iṣẹ wọn jẹmọ faaji naa maa sanwo ori lori ileeṣẹ wọn, anfaani to si wa ninu iforukọsilẹ ati owo ori sisan kii ṣe kekere.

"Iforukọsilẹ ni yoo ran ijọba lọwọ lati le maa mojuto eto aabo wọn. Bakan naa ni owo ori ti wọn ba n san yoo fun ijọba lanfaani lati le maa ṣe ojuṣe rẹ ninu ipese ohun amayedẹrun faraalu."

O ṣalaye pe lẹyin apero ọlọjọ meji yii, eyi to waye lati jẹ ki awọn ti ọrọ kan mọ ojuṣe wọn si ijọba, ohun to ku bayii ni ki ijọba bẹrẹ síi gbe igbesẹ ofin pẹlu awọn to ba tapa si ofin ijọba 

O ni "Igbesẹ mẹta ni ijọba gbe kalẹ lati ri i pe awọn ileeṣẹ to jẹ mọ afẹ tabi igbadun ṣeto iforukọsilẹ ati owo ori sisan, akọkọ ni lati ṣawari awọn ti ko tii forukọ silẹ, ekeji ni lati ba wọn sọrọ, ki wọn le mọ ojuṣe wọn sì ijọba, ikẹta ni lilo ọwọ ofin lati ri i pe awọn eeyan ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe.

"Inu Oṣu Kẹwaa ọdun yii la maa bẹrẹ sii lo ọwọ ofin, nigba naa nijọba yoo bẹrẹ síi da sẹria fawọn to ba kọ lati pa ofin iforukọsilẹ taa gbe kalẹ yii mọ."

Ọlatunbọsun waa gba awọn oludasilẹ ileṣẹ naa niyanju lati ṣamulo iwọnba asiko to ku ki oṣu to n bọ yii pe lati ṣe iforukọsilẹ Ileeṣẹ wọn 


Bakan naa laṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Ila-Oorun ati Iwọ-Oorun Ọyọ nIleegbimọ aṣojuṣofin, Ọnarebu Ọlọrunpọtọ Rahman, ṣalaye pe ipa pataki ni iforukọsilẹ ati owo ori sisan lori ileeṣẹ ni ko nipa bi ijoba ṣe ni pèsè eto aabo tawon ohun amayedẹrun gbogbo.




AWORAN
Kọmiṣanna fun aṣa ati Irinajo afẹ
Ọmọwe WasiubỌlatunbọsu.

No comments:

Post a Comment

Pages