Eyi ni bi awọn China ṣe n fi aṣa Yoruba lu Naijiria ni jibiti - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 23 September 2026

Eyi ni bi awọn China ṣe n fi aṣa Yoruba lu Naijiria ni jibiti


Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọpọ awọn ọmọ Yoruba to n wọ aṣọ ibilẹ ni wọn ro pe awọn n gbe aṣa abinibi wọn ga laimọ pe eto ọrọ aje orilẹ-ede ilẹ okeere, paapaa, ilẹ China ni wọn n gbe larugẹ.

Awọn onimọ ijinlẹ nipa aṣa ilẹ Afrika ni Fasiti Ibadan ni wọn sọrọ yii nibi apero ìmọ̀ kan ti wọn pe ni Ori Africa Hangout, 
ẹlẹẹkeji iru ẹ, to waye lỌjọ Abamẹta, Satide, Ọjọ Kejila, Oṣu Kẹsan-an, Ọdun 2026 yii.

Kọmiṣanna fun Aṣa ati Irinajo Afẹ ni Ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun lalejo pataki nibi eto ọhun to waye ni gbọngan iṣẹnbaye, National Museum lAlẹṣinlọyẹ, n'Ibadan.

Nigba to n sọrọ nibi eto naa, olukọ imọ nipa aṣa ilẹ Afrika, ni Institute of African Studies, ni University of Ibadan, Ọmọwe Ọladapọ Ajayi,
fidi ẹ mulẹ pe, ọpọ ninu awọn to n wọ aṣọ ibilẹ lati gbe aṣa Yoruba ga ni wọn ko mọ pe eto ọrọ aje ilẹ okeere lawọn n ṣe bẹẹ gbe larugẹ.

O ni taa ba n sọrọ nipa agbega aṣa, "O nii ṣe pẹlu ọrọ aje. O ṣeni laaanu pe awa ko ni ẹrọ to n pese aṣọ atawọn nnkan mi-in taa fi n gbe aṣa wa larugẹ.

"Netherlands ni wọn ti nṣe ọpọ ninu awọn aṣọ ankara ti a n wọ tẹlẹ, China ti tẹwọ gba a bayii, koda, wọn ti n hun aṣọ ofì ati adirẹ. Awọn China wọnyi ti mọ iru nnkan taa fẹran lati maa lo, awọn wa n fi ẹrọ pese wọn lọpọ yanturu.

"Ohun ti eyi tumọ si ni pe taa ba ri ọpọ awọn to n wọ aṣọ ofi tabi adirẹ eto ọrọ aje China ni wọn n gbe larugẹ nitori awọn ni wọn n pese pupọ ninu awọn nnkan wọnyi."

Ọmọwe Ajayi ṣalaye siwaju pe "Aṣọ adirẹ tiwa ti a n ṣe nilẹ Yoruba paapaa, ilẹ okeere bii China la ti n ra awọn ohun eelo rẹ wa nitori a ko moju to awọn eweko ti a n lo lati fi pese awọn aṣọ wọnyi funra wa. Itumọ eyi ni pe eto ọrọ aje ilẹ okeere la n fi eyi to pọju ninu owo wa gbe larugẹ.

Gbajugbaja obinrin oniṣowo kan, Abilekọ Aderinsọla Ogunlẹyẹ, to jẹ oludasilẹ ileetaja aṣọ April Fabrics n'Ibadan, kin olukọ Fasiti Ibadan naa lẹyin, o ni awọn ara China ni wọn n ṣe eyi to pọ ju ninu awọn aṣọ adirẹ ati ankara lasiko yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Ọpọ eeyan lo n lọọ ra kanpala lọja laimọ pe ankara loun fi owo ra ti oun n wọ. Ti kii baa ṣe awa taa jẹ alaṣọ tabi eeyan to ba da aṣọ mọ daadaa, o ṣoro pupọ lati mọ iyatọ laarin aṣọ adirẹ ati ankara ti awọn ara China ni ṣe nitori nṣe ni wọn ṣe awọn ankara yii bii aṣọ adirẹ gẹlẹ.

"Ṣugbọn teeyan ba ri wọn nibi ti wọn ti n ṣe aṣọ adirẹ lAbẹokuta, ti eeyan ri bo ṣe n gba wọn ni ọpọlọpọ asiko ati ọpọlọpọ eroja to, oluwarẹ yoo ti mọ pe o gbọdọ gbowo leri. Idi si niyi to ṣe jẹ ojulowo laṣọ adirẹ Abẹokuta ṣugbon adirẹ China maa n bẹ, o si maa n tete ya."

Obinrin alaṣọ naa tẹsiwaju, o ni "Bi aye ba ṣe n yi la n ba aye yi. Awọn ara Yúróòpù n ran wa lọwọ lati mu idagbasoke ba aṣa wa. Nigba mi-in, eeyan aa wọ aṣọ to bojumu lọ sọfiisi laimọ pe ankara loun wọ.

Nigba to n sọrọ nipa imura ni ilana ọmọluabi, Ọgbẹni Akeem Aṣiyanbi, ti oun naa jẹ olukọ ẹka Institute of African Studies, ni Fasiti Ibadan, sọ pe "Aṣa ko duro soju kan. Taa ba n sọrọ nipa imura ọmọluabi, a ni lati mọ nipa bi ẹya kọọkan ṣe n ṣe lọdọ kaluku wọn.

"Awọn ẹya kan wa to jẹ pe ti wọn ba ti da aṣọ bora bayii, wọn ti mura tan niyẹn. Awọn kan wa to jẹ pe iro lọkunrin tiwọn maa n ro iro mọ idi, bẹẹ imura obinrin nikan ni iro jẹ ninu aṣa mi-in."

"Ko si ohun to buru ninu ka maa fi aṣọ ibilẹ wa ran ara aṣọ atọhunrinwa. Bi emi ṣe n fi aṣọ ankara ran ṣẹ́ẹ̀tì ti mo n wọ lojoojumọ niyẹn. Ọmọ mi ọkunrin ati gbogbo idile mi naa si ti tẹwọ gba a, ankara ati kanpala la n wọ nile tiwa.

Ninu ọrọ tiẹ, oludasilẹ Ori Africa, ajọ olukufẹ ohun ini ilẹ Africa, to ṣagbekalẹ eto yii, Oloye Ọlanipẹkun Ọlalẹyẹ, ṣeleri pe gbogbo ohun ti awọn olujiroro tọka si nibi apero ọhun ni ajọ Ori Africa yoo gbe lọ sileegbimọ aṣofin lati ri i daju pe ijọba lu u lontẹ ofin.

Bakan naa lo kan saara si ijọba Gomina Ṣeyi Makinde lori agbega aṣa, o ni "Ijọba ipinlẹ Ọyọ gbiyanju, ẹẹmeji ni wọn faaye gba awọn oṣiṣẹ ijọba lati maa wọ aṣọ ibilẹ lọ sibi iṣẹ.

"Ṣugbọn ojoojumọ lawọn ara Oke Ọya n wọ aṣọ ibilẹ lọ sibi ni tiwọn. Gbogbo Ileeṣẹ aṣọ ibilẹ wa paapaa lo ti ku tan."

Ṣaaju ni Kọmiṣanna fun Aṣa ati Irinajo Afẹ ni Ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun, gba ajọ naa niyanju lati fẹsẹ mulẹ daadaa ni Naijiria na ko too di pe wọn gbe itaniji nipa aṣa ilẹ Afrika wọ ilẹ okeere nilẹ Afrika gbogbo.

Bakan naa lo rọ wọn lati ma ṣe gbẹkẹ le iranlọwọ ijọba bi wọn ba n fẹ lati ni ipa gidi lawujọ pẹlu aṣeyọri.






No comments:

Post a Comment

Pages