Ọlawale Ajao
Bii eeyan ba ri bi awọn ọmọ ati iyawo awọn ọlọpaa to padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ ṣe n sunkun lOlu Ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ọyọ lẸlẹyẹle n'Ibadan, tọhun yoo ro pe nṣe lẹni ti wọn n tori ẹ sunkun ṣẹṣẹ jade laye, bẹẹ o ti to ọdun meje sẹyin ti omi-in ninu wọn ti filẹ ṣaṣọ bora.
Kii ṣe ibanujẹ ipapoda olori ẹbi wọn nikan lo mu ẹkun gbọn wọn, ẹbun owo nla ti CP Olugbenga Abimbọla Ayọdeji, tii ṣe Ọga Agba Ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ọyọ fi ta wọn lọrẹ lojiji lo n pa wọn nigbe.
LỌjọbọ, Tọsidee, Ọjọ Kẹtadinlogun (17), Oṣu Kẹjọ, Ọdun 2026 yii ni CP Ayọdeji fun idile awọn ọlọpaa mejidinlaaadọta (48) ti wọn ṣalaisi lẹbun owo naa, owo to n lọ bii miliọnu mejidinlogoji (₦38.9m) Naira ni wọn pin fun wọn.
Nigba to n fun awọn aṣoju idile kọọkan ni sọwedowo kaluku wọn, ọga awọn agbofinro ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe igbesẹ yii jẹ ara eto adójùtòfò (ìǹṣọ́ráǹṣì) ti Ọga Agba Ileeṣẹ Ọlọpaa nilẹ yii, IG Ọlatunji Rilwan Disu, gbe kalẹ lati ri i pe awọn ọlọpaa to ku lẹnu iṣẹ ko fara jiya fun Naijiria lasan.
Ṣugbọn kii ṣe awọn to ba iku oro pade lasiko ti wọn wa ninu aṣọ ọlọpaa gan-an nikan ni wọn fun lẹbun owo ọhun, gbogbo ẹni to ba ku lasiko to ṣi jẹ oṣiṣẹ Ileeṣẹ ọlọpaa laifi ti iru iku to pa wọn ṣe, titi dori awọn to ṣaisan, atawọn ti wọn fọwọ rọri ku ninu ile wọn ni.
Gẹgẹ bi meji ninu awọn ọmọ ọlọpaa to janfaani eto ọhun ṣe sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin wa ,Ayilara Victoria, to jẹ ọmọ ọlọpaa to n jẹ Ayilara Sunday Francis, ṣalaye pe "Baba mi ku lọdun 2019. A dupẹ pe wọn fun wa lowo lonii.
"Ohun to pa mi lẹkun nigba ti CP fun mi ni sọwedowo ni pe ko pẹ ti dadi mi ku ni mọni mi naa ku. Awa mẹta ni wọn bi.
"Ọdun ti mo wọ ileewe poli ni baba mi ku. Nnkan ko rọrun rara fun awa mẹtẹẹta lẹyin iku awọn obi wa mejeeji ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun, emi naa ti jade ileewe bayii. A mọ riri owo ti ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fun wa lonii gidi gan-an ni."
Ninu ọrọ tiẹ, Oluwaṣeyi Badmus Babiímisí, ti oun naa jẹ ọmọ ọkan ninu awọn ọlọpaa to ti ṣalaisi, ṣalaye pe "Aisan lo ṣe dadi mi ti wọn fi ṣalaisi lọdun 2020. Inu wa dun pe Ileeṣẹ ọlọpaa fi owo ran idile wa lọwọ. Mọmi wa ni mo maa lọọ fun ni ṣẹ́ẹ̀kì yii ti mo ba dele.
Diẹ lara awọn to janfaani ẹbun owo ọhun ni Abilekọ Akintunde Jumọkẹ Sherifat, Akintunde Alex Ọlamide, Dada Ọmọdọlapọ, Odeh Keji, Ogunwusi Esther, Abeeb Abdullahi Ayọfẹ, Ayilara Esther Yẹmisi, Ọlaoye Ọmọlọla Demilọla, Ọlaoye Oluwatosin, Oluwaṣeyi Badmus Bababimisi, ati Aderintọ Oluwaṣeyi Abidemi.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin eto naa, CP Olugbenga sọ pe "Ohun taa ṣe lonii jẹ ara eto ìǹṣọ́ráǹṣì ti Ọga Agba Ileeṣẹ Ọlọpaa nilẹ yii, IG Ọlatunji Rilwan Disu, gbe kalẹ lati ri i pe wahala awọn ọlọpaa to ku lasiko ti wọn wa lẹnu iṣẹ aabo ilu ko fara ja sasan.
"A ti fun awọn ẹbi wọn lowo, a si ti gba wọn nimọran lori bo ṣe yẹ ki wọn na owo yẹn, ṣugbọn a ko nii tẹle wọn lọ sile lati maa ṣọ bi wọn yoo ṣe maa na a.
Bi awọn to padanu ẹmi wọn nigba ti wọn ṣi wa lẹnu iṣẹ ko ṣe si laarin wa mọ ko tumọ si pe a gbagbe wọn, loorekoore la maa n pe awọn mọlẹbi wọn lati beere alaafia wọn.
"Owo taa fun wọn yii paapaa ko pari sibẹ, a o tun maa fun wọn bẹẹ naa lọjọ iwaju.
Ni ibamu pẹlu ibeere oniroyin wa, Cp Ay ọdeji ṣalaye pe "Awọn ọlọpaa to padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ agbofinro ati aabo ilu lọdun yii ti pọ, ṣugbọn gẹgẹ bii baba rere fun gbogbo wọn, kii ṣe ohun idunnu fun mi lati maa ka iye ọmọ tl kaluku mọ mi labẹ."
O waa gba awọn eeyan naa nimọran lati
ri i daju pe wọn na owo ti wọn fun idile kaluku wọn daadaa paapaa lori eto ẹkọ awọn ọmọ ti awọn oloogbe wọn fi saye lọ.
No comments:
Post a Comment