Eyi jẹ lara abajade ipade awọn alaṣẹ ipinlẹ Ogun to waye lọjọbọ, Tọsidee ana. Nibi ti wọn ti jiroro lori igbesẹ iṣejọba Gomina Dapọ Abiọdun lori ọna ti wọn n gba lati fopin si awọn iwa ọdaran kaakiri ipinlẹ naa.
Bẹẹ ni wọn ko fẹẹ ki ipinlẹ Ogun tẹsiwaju gẹgẹ bi aṣaaju ninu lorileede nibi ti ifọkanbalẹ ti wa fawọn onileeṣẹ ati okoowo nla.
Aba naa ti wọn n gbero ẹ yii ni wọn pe "Group Liability For Offences of Violence, Extortion and Secret Societies, ti adape ẹ jẹ GLOVES , to tumọ ijiya fawọn ẹsun idaluru, gbigba riba ati ẹgbẹ okunkun lawujọ.
Adajọ agba nipinlẹ Ogun, Onidajọ Oluwaṣina Ogungbade ṣalaye pe akojọpọ awọn aba naa da lori ofin ti yoo lori awọn iwa ọdaran to le mu adinku ba ijakulẹ eto abo.
Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn ofin naa lẹyin ti wọn ba gba awọn aba naa wọle yoo ba gbogbo iwa ẹgbẹkẹgbẹ jẹ yoo si jẹ ki wọn sọ agbejẹ mọwọ.
Bakan naa ni Ogungbade tun ṣalaye siwaju pe awọn ofin yii yoo tun dẹkun awọn to afẹmiṣofo atawọn to n feeyan ṣogun owo pẹlu.
Bakan naa lo ni aba lori beeyan ba sọnu lojiji, to ni wọn yoo maa ṣewadii lori bi wọn ko ba ri eeyan, lati mọ onitọhun, awọn wo lo wa ni ijinigbe ẹ atawọn ti wọn ba fura si pe o ji i gbe.
Ogungbade waa sọ pe awọn aṣofin ati Gomina Dapọ Abiọdun ni wọn jọ n ṣiṣe pọ lori bi abo yoo ṣe fẹsẹ rinlẹ daadaa, ki
alaafia le jọba, ki ọrọ aje si maa lọ bo ṣe yẹ.
Adajọ agba nipinlẹ naa wa ṣeleri pe laipẹ yii ni wọn yoo fi abadofin ọhun ranṣẹ sile igbimọ aṣofin.
No comments:
Post a Comment