Nitori ki eto abo tun le rinlẹ; Ajọ aṣọbode, ileeṣẹ oloogun ati ajọ to n gbogun ti ogun oloro fẹẹ sowọpọ lati gbogun tawọn onifayawọ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 1 August 2026

Nitori ki eto abo tun le rinlẹ; Ajọ aṣọbode, ileeṣẹ oloogun ati ajọ to n gbogun ti ogun oloro fẹẹ sowọpọ lati gbogun tawọn onifayawọ.

Lati le gbogun tawọn onifayawọ lawọn ẹnu bode to paala pọ pẹlu ipinlẹ Ogun, ajọ aṣọbode, ileeṣẹ ologun ati ajọ to n gbogun ti ogun oloro, NAFDAC, ti pawọpọ ki wọn le jọ ṣiṣẹ pọ.

Ọga agba fajọ aṣọbode ti ẹkun kin in ni nipinlẹ Ogun, Ọladapọ Kayọde Afẹni tun ti sọ pe oun atawọn alaabo tun ti tẹsiwaju lati jọ ṣiṣẹ pọ lawọn ẹnubode to paala lati fopin si awọn onifayawọ.

O sọrọ yii lakooko ti ọga to n gbogun ti ayederu ounjẹ ati ogun oloro,Dokita Martin Iluyọmade ati ọga agba ologun nipinlẹ Ogun, Ọgagun Friday Onuche Onu,ṣabẹwo lọtọọtọ lọ sọdọ Afẹni.

Gẹgẹ bi Iluyọmade ṣe wi, o ni ipese abo lawọn ẹnubode ki i ṣe nnkan ti aṣọbode nikan le da ṣe nitori ẹ lawọn ṣe gbọdọ fọwọsowọpọ lati le gbogun tawọn to n ko ayderu ounjẹ atawọn ogun oloro wọlu.

O waa gboriyin fawọn aṣọbode fun ti awọn akọsilẹ rere ti wọn ni lori igbogun ti gbigbe awọn ounjẹ ati aṣilo ogun wọlu.

Ninu ọrọ ti Ọgagun Onu lo ti bẹbẹ fun itẹsiwaju ajọṣepọ to danmọran laarin ileeṣẹ mejeeji.

O ni lara iṣẹ wọn ni lati gbogun tawọn fayawọ nipa ibaṣepọ awọn ati aṣọbode, o waa ṣeleri pe gbogbo ọna to ba yẹ lawọn yoo dide iranlọwọ lati le jẹ ki abo fẹsẹmulẹ.

Ninu ọrọ Afẹni lo ti dupẹ lọwọ awọn ileeṣẹ mejeeji, pẹlu ileri pe awọn yoo tubọ maa farajin lati rii pe fayawọ di ohun itan nipinlẹ Ogun.

No comments:

Post a Comment

Pages