Onitafin ti Orile-Tafin fẹẹ ṣayẹyẹ aadọrin ọdun bẹẹ ni yoo tun fi ọga oniroyin Fọlake Adunni Adeyẹmi joye Aṣiwaju Yeye Oge - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 31 July 2026

Onitafin ti Orile-Tafin fẹẹ ṣayẹyẹ aadọrin ọdun bẹẹ ni yoo tun fi ọga oniroyin Fọlake Adunni Adeyẹmi joye Aṣiwaju Yeye Oge


Gbogbo eto lo ti to fun ayẹyẹ ọjọọbi Onitafin Orile-Tafin, Ibarapa nilẹ Ẹgba, Ọba Moruf Alani Ọlalekan Adebayọ,fun ti ayẹyẹ ọjọọbi aadọrin ọdun to fẹẹ ṣe.

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ, ọjọ mẹrin ni wọn ti la silẹ fun ayẹyẹ ọhun ti yoo bẹrẹ ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin si ọjọ Ẹti, Furaide,ọjọ keje, oṣu kẹjọ ọdun yii.

Lara awọn eto alarinrin ti wọn ti la silẹ fawọn ọjọ naa ni ifinijoye, ironilagbara, idanilẹkọọ ati iwẹjẹwẹmu.

ifinijoye ni yoo kọkọ bẹrẹ lọjọ Tusidee, ọjọ Kẹrin, oṣu kẹjọ, lara awọn ti yoo joye lọjọ naa ni gbajumọ to tun jẹ agba oniroyin nni, Fọlakẹ Adunni Adeyẹmi, ni Ọba naa yoo jawe oye le e lori gẹgẹ bi Aṣiwaju Yeye Oge Orile-Tafin atawọn mii-ii.

Lọjọọru, Wẹsidee, ni Ọba Alani Adebayọ yoo tun ṣabẹwo lọọ sọdọ Onibara tiluu Ibara, Ọba Jacob Olufẹmi Ọmọlade, bẹẹ ni wọn yoo tun dele Oloye Joseph Fọlarin Ọdunjọ, agba onkọwe Yoruba nni lati fi ṣeranti awọn ipa to ti ko ninu eto ẹkọ lorileede yii, ti wọn yoo si fawọn ẹbi ẹ lawọn ẹbun.

Ọjọbọ Tọsidee ni idanilẹkọọ yoo waye ni Kabiyesi to wa ni Kugba nigba tayẹyẹ iwẹjẹ wẹmu fun ọjọọbi yoo waye lọjọ Furaide lati fi pari gbogbo eto.Emfelix Events and Coference Centre lọna OGTV, Abeokuta ni yoo ti waye.

No comments:

Post a Comment

Pages