Afẹni ṣeleri ajọṣepọ to danmọran pẹlu awọn eleto abo yooku lẹnu bode ilu. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 8 July 2026

Afẹni ṣeleri ajọṣepọ to danmọran pẹlu awọn eleto abo yooku lẹnu bode ilu.

Ọga agba fajọ eṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Ọladapọ Afẹni tun ti ṣeleri pe ajọṣepọ to danmọran yoo wa laarin wọn pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo yooku lati rii pe abo to peye wa lawọn ẹnu bode to mule ti orileede yii.

O sọrọ naa lakooko kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Bọde Ọjajuni, ṣabẹwo si ọdọ wọn ni oluuleṣẹ wọn to wa ni Idiroko, nipinlẹ Ogun.

O kọkọ dupẹ lọwọ awọn eleto aabo lori bi igbọraẹniye ati ifọwọsowọpọ ṣe wa laarin wọn, eyi to jẹ ki wọn maa ṣaṣeyọri lori awọn iṣẹ ti wọn n ṣe lati gbogun ti fayawọ.

O ṣalaye ipa ti ẹṣọ aṣọbode ko lati pa owo wọle, bẹẹ lo tun sọ pe nipa afojusun wọn lori eto ọrọ aje, okoowo  ati abo, eyi to ti nipa rere fawọn araalu, eyi to ni o ti mu idagbasoke rere wa nipasẹ ifọwọsowọpọ pẹlu awọn eleto abo yooku.

Afẹni tun menuba bi awọn ati orileeede Benin tun ṣe jọ n ṣiṣẹ pọ lẹnu aala to pa wa pọ, to tun ni ara aṣeyọri ti ko lẹgbẹ ni.

Ko sai mẹnuba a pe nigba toun ṣẹṣẹ gbaṣe bawọn ti wọn n wa kaakiri oju ọna ṣe pọ ṣugbọn ti adinku ti bawọn nipasẹ agbọye to wa laarin wọn.

O waa ṣeleri pe gbogbo ọna lawọn yoo maa gba gẹgẹ bi iṣẹ wọn lati pese abo fawọn araalu, ki awọn fayawọ si rin jinna rere nipinlẹ Ogun.

Ko to to akoko yii ni kọmiṣanna ọlọpaa Bọde Ọjajuni ti gboriyin fun ọga agba aṣọbode lori ipa to ti ko lẹnu igba to ti gba ipo nipa aabo, okoowo  ati ọrọ aje.

Bẹẹ lo tun mẹnuba bi alaafia ṣejọba ni idiroko ti gbogbo okoowo n lọ nirọwọ rọsẹ.Oun naa wa ṣeleri pe ajọṣepọ to wa laarin awọn mejeeji yoo tubọ maa tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

Pages