O sọrọ yii nigba ti ẹgbẹ awọn olootu iroyin Yoruba iyẹn League of Yoruba Media Practitioners ṣaọ́bẹwo lọ sọdọ rẹ. O ni awọn gan an ni ko ni jẹ ki ede ati aṣa parun lọjọ iwaju.
Ṣowunmi tun gboṣuba kare fun Aarẹ Tinubu fun awọn iṣẹ akanṣe aritọkasi to ti ṣe paapaa lẹka awọn ohun amayedẹrun.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, 'Bi ija ba wa nibẹ ka pari ẹ, Tinubu ṣiṣẹ to lapẹẹrẹ, eyi tawọn eeyan ma ranti fun ọdun pipẹ'. O mẹnuba aṣeyọri aarẹ lori ọrọ atunṣe owo ori, eyi to mu igbaye irọrun ba awọn mẹkunnu, yiyọ owo iranwọ epo lati ṣe iṣẹ akanṣe kaakiri awọn ipinlẹ, pipese owo iranwọ fawọn akẹkọọ iyẹn NELFUND ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O gba awọn ọmọ ilẹ kaarọ oojiire nimọran pe ki wọn ma ṣe pẹlu awọn atọhunrin kọyin sọmọ tiwọn nitoripe tẹni-n-tẹni.
Ṣowunmi sọ pe, iṣẹ pọ fun Aarẹ Tinubu lati ṣe, nitori naa lo ṣe gbọdọ lo ọdun mẹjọ rẹ pe.O ni gbogbo ọmọ Yoruba lo gbọdọ ṣatilẹyin fun Tinubu fun itẹsiwaju rere.
Ni ipari ọrọ rẹ, o ni, bi ọmọ Yoruba ba kọ lati ṣatilẹyin fun ipadabọ aarẹ lọdun 2027, oun ma binu si Aarẹ Tinubu gidigidi bo ba le fun ọmọ Yoruba kankan nipo ninu iṣakoso rẹ.
O ni bo tiẹ jẹ pe, eekan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mi ti mi o si nii lọkan lati kuro nibẹ ṣugbọn bi ija ba wa nibẹ ka
pari ẹ, Tinubu gbiyanju bẹẹ lawọn eeyan ṣi ma ṣadura fun titi aye.
Agba oloṣelu naa tun rọ awọn ọmọ ilẹ kaarọ oojire lati ma bu ọla fun ede abinibi ilẹ Yoruba, o ni orileede to ba sọ ede rẹ nu ti sọ idanimọ rẹ nu atipe yoo dabi orileede ti ko ni ẹyin ọla.
Ṣowunmi jẹ ko di mimọ pe, bi awọn obi ati alagbatọ ba kuna lati jẹ kawọn ọmọ wọn ma sọ ẹdẹ Yoruba, o ṣee ṣe kawọn ọdọ iwoyi koju iṣoro lọjọ iwaju latari bi wọn ko ṣe fẹran lati maa sọ ede abinibi wọn. O ni, ọrọ naa ko yọ awon olukọ paapaa silẹ, ṣe ni ki wọn mu kikọ ati sisọ ede abinibi wa ni pataki ni yaara ikẹkọọ.
Eekan oloṣelu naa wa rọ gbogbo ẹka igbohunsafẹfẹ ati iwe iroyin lati maa ṣe igbelarugẹ ede ilẹ kaarọ oojiire nigba gbogbo.
O tun lo asiko naa lati rọ aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati tubọ fẹsẹ imọ ẹkọ ede Yoruba mulẹ siwaju si i lawọn ileewe kaakiri ilẹ kaarọ Oojiire.
No comments:
Post a Comment