OJU OGBOLOGBO AJE NI MO FI MA NWO EGBON BABA MI TI MO GBE ODO RE SUGBON- KEMZY HERBAL - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 8 July 2026

OJU OGBOLOGBO AJE NI MO FI MA NWO EGBON BABA MI TI MO GBE ODO RE SUGBON- KEMZY HERBAL

Gbajumo Onisegun ibile ni Olukemi Sangotola Ajare ti o je Alase ati Oludari Ile ise Ìségun ibile KEMZY HERBALS.
Arewa obinrin ti o je Obabinrin Sango Oranfe Onile Ina Ile-Ife oun ni o gba gbogbo eniyan iyanju paapa lati tete pada si orirun ati ipile won.


Ofiisi re ti o wa ni nomba 3, Olugbede Street ni adugbo Oorelope, Egbeda ipinle Eko lo ti se iforowero pelu Aloba Adewunmi ti o je Olootu Agba iwe ìròyìn Agbenuso Adulawo The Mouthpiece.

Agbenuso: E ba wa se afihan ara yin fun awon onkawe Agbenuso Adulawo The Mouthpiece 


KEMZY HERBAL: Olukemi   Hanna Ajare gangan ni Oruko mi, omo bibi ilu Ihima ni ipinle Kogi ni mi, sugbon ilu Kaduna ni won bi mi si, ologun ( soldier ni baba mi ), bi won si se ngbe baba mi kiri ni o je ki emi naa gbe orisirisi Ilu kaakiri Orílè-èdè Naijiria, ki a to wa fi ibugbe si Kaduna leyin opolopo isikiri, ilu Kaduna ni mo ti lo si ile-iwe alakobere.

AGBENUSO: Obabinrin Sango Oranfe onile Ina niyin, leyi ti o fi han wipe onisese ni yin, sugbon Oruko ( Hanna ) fi yin han gege bi omoleyin Kirisiti, nje e le salaye idi ti eleyi fi ri bee?

KEMZY HERBAL: Haa Agbenuso! Ibeere nla ni e beere yi oo.. laarin ipari odun 80s si ibere odun 90s ni baba mi ko iwe fi ise ologun sile, nitoripe baba ati mama won ti dagba, gegebi asa ilu ati ebi wa, baba mi gegebi akobi omo, gbodo pada sile lati mojuto awon obi won, eleyi lo mu ki a fi ilu Kaduna sile wa si ilu Ebute Meta, ipinle Eko nibiti awon obi won tedo si lati Kekere, sugbon emi ko ba won gbe Eko rara. 


Ilaje ese odo ipinle Ondo, l'odo egbon baba mi to je agba obinrin oloselu nla ni ipinle Ondo ni mo gba lo, odo won ni mo ngbe, won fimi si Ile iwe girama, agba ninu ijo omoleyin Kirisiti nla kan ni won.

Odo mama yi ni mo gbe ti mo lo igba omidan mi, ara mama yi ni mo ti ko gbogbo eko ti mo nmulo loni gegebi akinkanju obinrin ti ko se fi owo ro séyìn laarin okunrin paapaa ka ma wa so laarin elegbe re obinrin.

Oloselu ni mama bi mo se wi, Oluko tisa ni won, beeni won je asiwaju kan gboogi ni Ile ise ijoba ibile kansu won ni Ilaje ese odo.

Agbe alada nla ti o nse ogbin ope, isu, koko, òniruuru eso paapaa ogede tun ni mama yi, akinkanju gbaa ni mama mi.

O dunmi wipe mo kuro lodo won nigbati ko ti ye ki nkuro nitori oro esin.

Alaga Abiye ninu egbé Ogboni onigbagbo iyen The Reformed Ogboni Fraternity ROF ni won nigbayen, bi maami se je Oluko wa je ki won je eniti o ma nfi owo ikoraeni ni ijanu mu omo leyi to je ki emi ro wipe won buru ju gegebi  ironu omode ti mo je nigbayen.

Mo darapo mo soosi igbalode, ti mo si je olufokansin, ni soosi igbalode yi ni won ti je ki ngba wipe ogbologbo aje ni mama yi, koda won riran si mi ni soosi wipe ejo nla kan wa ni abe beedi mama, iran ati awon asotele ideruba, buruku yi ati awon owo ibawi ife ti mama fi mumi sugbon ti ko yemi nigbayen ni mo se gba wipe ogbologbo aje ni mama mi yi looto, ti mo si bere si sara fun won, Inu Ile ti mama ko ni iyara aiwo fun enikeni wa di eru fun mi, yara mama ti mo nsun si pelu abe beedi won ti mo ti ma nsere sun si lopo igba wa di igbo erujeje funmi.


Emi ni mo ma nfo aso itagbe nla ti mama ma nwo, ti ma si ka sinu baagi nla ki nto ba won gbe lo si conclave won lojo ipade ROF, ni kete ti mo ti gba esin soosi igbalode yi ni wahala ti de bami ti mi o si le gbe ni alaafia pelu oloore mi mo.

Inu ijo yi ni won ti so funmi wipe a fi ki nkuro ninu Ile yi, ni ileri Olorun fun aye mi le se, nitoripe awon agbara okunkun kan wa ti ejo nla ti o ngbe abe beedi maami nse akoso re, won ni a fi ki nkuro nibe.


" Nitorinaa egbe aje ni mo ma npe egbe awon iya abiye nigbayen, ti mo si ma nfi owo so aya ninu aimokan wipe mo mo ibiti awon aje ti nse ipade ati wipe egbon baba mi ti mo ngbe odo won ni olori awon aje ni gbogbo agbaye" sugbon loni emi naa ti di iya abiye Iledi Asiwaju Debo Omotosho Ikeja l'Eko leyin opolopo odun, erin arintakiti ni mo si ma nfi ara mi rin ti mo ba ti ranti irinajo mi pelu mama mi yi.

AGBENUSO: Eyin ni oludasile ati adari Ile ise Ìségun ibile KEMZY HERBALS, bawo ni e se de idi ise Ìségun ibile, kini erongba yin ti e fi da ogbon iwe ati olaju po mo ise isegun ibile.

KEMZY HERBAL: Ibeere nla ni e beere yi ooo, nkan ti o sele ni wipe, leyin ti mo kuro nile, mo wa ise se Okan mi si poruuru gan asiko yi ni agbara Inu mi ati agbara irori mi bere si se awari oun ti mo je gan, ibiti mo ti nsise ni mo ti Koko pade omokunrin elesin musulumi alu suna kan tebiliigi ni, o bami soro Ife nigbayen mo si gba fun, oun naa ni okunrin akoko ti mo koko gba lati fe, osù meta pere ni a fi jo rin irinajo ki a to mo wipe ebi ni wa, bi mo se fi omokunrin naa sile ni mo ju ijaabu nu ti mo si pada si soosi, ko pe ni mo ko owo jo ti mo si wo unifasiti ipinle Eko LASU, Ile iwe yi ni mo wa ti won fi gbe pasito kan ti o je odo langba wa si Ile ijosin wa, pastor yi lo nawo si mi lojo kan laarin opo eniyan ti o si so gbolohun oro meji ti o yi aye mi pada titi di oni.


Pasito Titus lo nawo si mi ti o ni " Sister Kemi Pick up Your Pen for an Assignment and Take care of your Spiritual Companion" soosi wa kii se serafu, cele tabi C A.C ijo igbalode ti o gbajumo kaakiri Orílè-èdè agbaye loni ni, Koda ko si inu ebi kan ni Naijiria ti ko si omo ijo yi lowo bayi.

Oro ti pastor Titus so lojo yen ni o bere si gbile lo kan mi, itumo oro mejeeji ni mo nwa kiri idahun si awon ibeere Oro mejeeji naa, lo so mi di oun ti mo da loni, gegebi Olorisa ati Onisegun ibile.


Oju mi ri gan lowo awon onijibiti ati alonilowogba ti won nfi isese boju sise ibi won ooo.. ki nto ri idahun si ibeere Okan mi, gegebi agbomola, ipe agbomola ni ise Òrìsà ati isegun ibile, sugbon ise Ìségun ibile ni a le mu ni ise owo ti a fi le ri owo gbo bukaata, ise iranwo ati idagbasoke emi ni olorisa nse ise iranse ti ko so le so eniyan di oloro kiakia ni ise Òrìsà, ise idoti ni mo ma npe ise isegun ibile latijo, sugbon ni bayi omowe ni awon onisegun ibile, idagbasoke ati iyato nla lo ti ba ise isegun ibile.

AGBENUSO: Abiye niyin ninu awo Ogboni Reformed Ogboni Fraternity, kini ipa yin, ninu iledi yin, kini idagbasoke ti awo yi mu ba awujo.

KEMZY HERBAL: Hmmmm esin atokeere wa ati eko won lo mu asigbo ba ise, asa ati eto iselu Ile adulawo, Ile Yoruba ni ona ati eto ti a ngba se ilu ti otito ati iberu Olodumare pelu ife pelu alaafia fi joba laarin awon baba nla wa nigbakanri.


Esin igbalode ati awon eko ti won nko awon eniyan lo, da omi alaafia Ile Yoruba ru, esin igbalode lo ko eyin gbogbo wa si ara wa to wa di wipe awa nberu ara wa.

Reformed Ogboni Fraternity je egbe ti o nkoni ni iwa omoluabi ati Ife otito si omolakeji eni, qgbekale eto ROF lo ko onigbagbo lati je onigbagbo looto ninu oun gbogbo ti o ba gbagbo idi re gan si niyen ti won fi ma npe The Reformed Ogboni Fraternity ni ogboni onigbagbo. ipo mi gegebi iya abiye ni lati ri wipe ife aisetan, alaafia joba lawujo ti mo ba ti ba ara mi, alatunse ni awon iya abiye.

AGBENUSO: kini Imoran yin fun awon, odo, obinrin ati awon ti won sese nbo ninu Isese?

KEMZY HERBAL: Haaa Imoran mi ni ki won o la oju won daadaa, ki won fi ara bale ko eko, Isese je irinajo ti o tobi pupo, ki gbogbo eniyan se awari ara won lokan won, ki won to gba Imoran lowo enikeni, ki won si se iwadi enikeni ti won ba fe mu gegebi olutosona won ninu irinajo Isese ao ni bo s'owo o.

No comments:

Post a Comment

Pages