O sọrọ yii lakooko to n jabọ iṣẹ irinu wọn fun saa keji ọdun yii iyẹn lati inu oṣu kẹrin si kẹfa ọdun yii, eyi to waye ni Idiroko.
O sọ pe pẹlu bawọn ṣe n fojoojumọ gbogun ti wọn lati dinku sibẹ awọn kan ṣi wa ti wọn ti pinnu lọkan wọn pe wọn ko nii jawọ, idi ẹ lawọn naa ṣe fojoojumọ fi ogun ja wọn.
Afẹni ṣalaye pe ọpọ awọn aṣeyọri lawọn ti ṣe laarin oṣu mẹta to kọja yii.O sọ pe owo to to N259,277,346.89 ni wọn pa wọlẹ. O ni eyi peleke soke ju ti sa akọkọ ọdun yii lọ eyi to jẹ N182,445,543.89
Afẹni tun mẹnuba a pe lara awọn nnkan tawọn gba lọwọ awọn fayawọ laarin oṣu mẹta saa keji ni oogun oloro, loriṣiriṣi,apo irẹsi, aloku aṣọ, epo pẹtiroolu atawọn nnkan mii-ii .
O sọ pe ibẹrẹ oṣu yii lawọn oṣiṣẹ wọn to wa ni Ijẹbu Ode, rọwọ mu mọto tirela kan to kun fun aloku taya mọtọ, eyi to saaba maa n ṣokufa ijamba mọto.
Bẹẹ lo tun sọ pe awọn tun ri awọn apo irẹsi ti wọn fẹẹ ko wọlu gba pẹlu iyẹn lọna Afamin Igbogila.
O tẹsiwaju pe iṣẹ kekere kọ lawọn n ṣe nipa eto aabo pẹlu awọn eleto aabo yooku ni ẹnu ibode ilu nibi toun ti jẹ alaga wọn.
O wɛ lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ alaabo yooku atawọn araalu fun ifọwọsowọpọ ati atilẹyin ti wọn ri gba.
No comments:
Post a Comment