Ọkunrin naa sọrọ yii nibi ti igbimọ alakoso ọhun ti ṣe ipade pọ pẹlu awọn oniroyin lati fi le tan imọlẹ sawọn ẹsun ọhun.
Nibi ọjọ mẹta kan sẹyin lawọn kan ninu ẹgbẹ ADC Ogun fi atẹjade lẹta ti wọn kọ si awọn adari wọn niluu Abuja nibi ti wọn ti fi ẹhọnu wọn han bi alaga ẹgbẹ wọn, Fẹmi Ṣoluade ṣe n dari ẹgbẹ wọn lọna aitọ, nipa lilo ipo to wa lati jẹ gaaba, ṣiṣe owo baṣubaṣu ati iwa aitọ ti wọn lo n hu sawọn obinrin ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ṣugbọn awọn alakoso eto iroyin, ikansiraẹni ati ipolongo ti ni ko si ootọ nibẹ ati pe ẹtanu oṣelu ni wọn n lo.
Adeṣina ṣalaye siwaju pe lẹyin tawọn ti ṣe agbeyẹwo lori awọn ọhun,awọn rii pe awọn tọ lẹta ẹhọnu naa fẹẹ fi da wahala silẹ.
O sọ pe rii gbogbo ẹsun ọhun dabi ẹni ti wọn tako ara wọn, ti awitunwi si tun pọ nibẹ pẹlu.
Ati o ni wọn fẹẹ lo lati fi le ka ara wọn gẹgẹ bi ikọ kan ninu eyi to sọ pe ko bofinmu, eyi to ni wọn ko ṣetẹwọgba.
Awọn alakoso tun tẹsiwaju ninu ọrọ wọn pe ohun to ṣe pataki ju ninu ẹ ni pe Ọtunba Fẹmi Ṣoluade wẹ mọ lori ẹsun owo baṣubaṣu ti wọn fi kan an.
O ni, " A ni awọn iwe ẹri kan taa fẹẹ fi gbe ọrọ wa lẹsẹ lori bi alaga ṣe nawo lọna to ba ofin ẹgbẹ mu.
Lori ẹsun pe alaga dari owo tawọn oludije fi gba fọọmu si osuwọn akaunti ẹ,Adeṣina ni ọrọ ko ri bẹẹ ati pe ko si bi wọn ṣe gbowo naa ni wọn san skaunti bsnki ẹgbẹ lapapọ niluu Abuja iyẹn Zeninth.
O sọ pe lori pe wọn sanwo sinu akaunti alaga wọn ki i ṣe ajọmọ tiẹ nikan, gbogbo agba ẹgbẹ naa lo mọ si ati pe o nigba to fi wa nibẹ.
Bakan n Adeṣina tun mẹnubaa pe Ọgbẹni Ọladimeji, to jẹ igbakeji akọwe iṣuna apapọ lo lọ siluu Abuja lati gba fọọmu akọkọ ni ọfiisi akọwe apapọ.
Ṣugbọn wọn ni kaka ko ko fọọmu silẹ fun alaga wọn, Ṣoluade, ṣe lo taku, koda wọn ni tipatipa lo fi ko mẹwaa silẹ ninu aadọta.
Wọn ni awọn fẹẹ ki gbogb ọmọ ẹgbẹ oṣelu ati araalu mọ pe akọsilẹ to peye lo wa bi wọn ṣe gba fọọmu oludije,orukọ awọn to gba a, iye ti wọn san,ọjọ ti wọn san owo pẹlu risiti ti wọn gba.
Bẹẹ ni iwadii tun jẹ kawọn mọ pe awọn ti wọn fọwọ si lẹta ẹhọnu ọhun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ ADC.
Wọn wa ni digbi lawọn agba ẹgbẹ oṣelu ADC, ti ko si iyapa, ti wọn si wa niṣọkan lati rii pe ẹgbẹ wọn tẹsiwaju.
Bẹẹ ni wọn rọ awọn araalu lati ma ṣe tẹti si awọn ahesọ to le maa da wahala silẹ
No comments:
Post a Comment