Paṣeda ni mo ṣetan lati dije fun sẹnetọ ni Ogun East - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 25 June 2026

Paṣeda ni mo ṣetan lati dije fun sẹnetọ ni Ogun East


Agba oṣelu nni Ọtunba Rotimi Paṣeda lo ti fi ipinnu ẹ han lati jade dupo fun sẹnetọ lati Ogun East, ninu ibo to n bọ lọdun 2027.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọkunrin naa sọ pe oun ko nigbagbọ pe wọn mu eeyan eyi tawọn oloyinbo pe ni Endorsement fun oludije kan.

Ilu Ijẹbu Omu lo ti sọrọ naa,o ṣalaye pe ifikunkukun si n lọ lọwọ lati jade fun ipo senetọ ọhun, eyi apejẹ ẹ yoo jẹ 'Pa Ṣe Wọn Da'

Paṣeda to ti figba kan jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu UPN nipinlẹ Ogun tun sọ pe ko si nnkan to jọ ọ pe koun darapọ mọ tabi ṣatilẹyin fun oludije kankan, bi ko ṣe pe awọn yoo jọ figagbaga.

O fikun ọrọ ẹ pe oun to ṣe pataki ni pe ki ẹgbẹ oṣelu atawọn olubaṣiṣẹ pọ ni Ogun East jọ niṣọkan lati ṣafihan ifarajin wọn nipa awọn igbesẹ to nitumọ ju ki wọn ma bẹ araalu.

O sọ pe oun nigbagbọ pe idibo ọdun to n bọ yoo faaye gba awọn oludije to kun oju oṣuwọn yoo si dara ju wọn darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mii-in.

Paṣeda tẹsiwaju pe oun ṣakiyesi pe awọn oludibo gan-an ti murasilẹ ti ṣetan lati dibo dun ẹgbẹ oṣelu ti wọn mọ pe o to gbangba sun lọyẹ.

O ni oju awọn eeyan ti kuro lori ẹgbẹ oṣelu bi ko ṣe adari to ba koju oṣuwọn ti wọn le jẹ ki araalu jẹ mudunmudun ijọba  tiwa-n-tiwa.

Agba oṣelu ọhun wa sọ nipa erongba ẹ lati jade dupo eyi to ni ipolongo oun yoo jẹ eyi ti yoo mu irọrun ati idagbasoke wa fawọn eeyan Ogun East.

O ni oun ṣetan lati ṣaaju awọn nnkan to le mu idẹrun bawọn eeyan agbegbe to fẹẹ lọ ṣoju fun ni Abuja.

No comments:

Post a Comment

Pages