Kayeefi lọrọ esi ibo alabẹsekele iyẹn ti ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun si n jẹ nigba ti wọn kede ẹ nitori bawọn ọnarebu marun-un, ti wọn si wa nile igbimọ aṣoju ṣofin lakooko ṣe ṣubu yakata ti wọn lulẹ patapata nibi ibo to waye ọhun. Koda a fi bi ẹni pe wọn fi ibo ọhun yẹyẹ wọn.
Awọn Ọnarebu ọhun ni Abiọdun Isiaq Akinlade to n ṣoju agbegbe Yewa South/Ipokia, Ọnarebu Tunji Akinosi,Ado Odo Ọta, Onarebu Ibrahim Isiaka,toun ṣoju Ifọ/ Ewekoro, Ọnarebu Adeṣọla Ẹgbẹji, toun ṣoju Rẹmọ North ati Ọnarebu Fẹmi Ogunbamwo
Awọn eeyan wọnyii ni wọn ti kọkọ jakulẹ ninu kọnsẹnsọsi amọ ti wo agidi sori, ti wọn lawọn ko gba ti wọn lọọ gba fọọmu fun pamari, nibẹ waa ni wọn ti fi ibo yẹyẹ lọjọ Abamẹta to kọja yii.
Nigba to n kede esi ibo pamari fun aṣoju ṣofin APC to waye ọhun,Kọmureedi Shuaib Phillips to jẹ alaga igbimọ to ṣeto ọhun nipinlẹ Ogun, lo ti darukọ awọn mẹsan-an to jawe olubori gẹgẹ bi oludije wọn.
Awọn naa ni Ọnarebu Olumide Ọṣọba fun agbegbe Ọbafẹmi Owode, Ọdẹda ati Abẹokuta North. Ọnarebu Motunrayọ Adijat Adelẹyẹ,Ifọ/ Ewekoro, Ọnarebu Ọlanrewaju Baṣọrun fun agbegbe Ado Odo Ọta.
Ọnarebu Rasak Dahdah fun aarin gbungbun Ijẹbu, Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, fun ẹkun Yewa North/ Imẹkọ Afọn, Dokita Toyin Taiwo, Yewa South/ Ipokia.
Awọn yooku ni Ọnarebu Afọlabi Afuapẹ fun Abẹkuta South, Ọnarebu Funmi Ẹfuwapẹ fun Rẹmo North ati Ọnarebu Joseph Adegbesan to wọle fun ẹkun Ijebu North East/ Ogun Warerside.
No comments:
Post a Comment