Awọn alaga wọọdu Ogun Central ni ki Shuaib Salisu fọkanbalẹ fun ipo Sẹnetọ lẹẹkeji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 17 May 2026

Awọn alaga wọọdu Ogun Central ni ki Shuaib Salisu fọkanbalẹ fun ipo Sẹnetọ lẹẹkeji


Awọn alaga wọọdu lawọn ijọba ibilẹ to wa ni Ogun Central ti sọ fun Sẹnetọ Shuaib Salisu pe ko maa mi kan didun lọsan yoo so nibi ipade pamari ti yoo waye lọla yii.

Nibi ipade ti wọn ṣe ni papa iṣere MKO, kutọ niluu Abẹokuta lawọn eeyan naa ti sọrọ yii lakooko ti wọn kede pe oun ni oludije ti wọn fọwọ si laini atako rara.

Gẹgẹ bi Alaaji Ọlalẹyẹ to ṣaaju wọn ṣe wi, o ni gbogbo wọọdu mẹrinlelaadọrin to wa ni Ogun Central lawọn jọ fọwọ si igbesẹ naa, tawọn yoo si ṣatilẹyin fun un.

Wọn nidii pataki tawọn fi sọ pe ki Shaibu maa ba iṣẹ ẹ lọ lawọn ipa takuntakun to ti ko eyi to ti mu idagbasoke ba Ogun Central titi di akoko yii.

Wọn wa lawọn panupọ muu gẹgẹ bi kọsẹnsọsi oludije wọn lati ṣoju wọn nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja.

No comments:

Post a Comment

Pages