Ìṣòro àìfọkàntán, àkóyawọ́ àtàwọn mí-ìn lẹ́ka ìdarí nínú ẹgbẹ́ Gomina Onitẹsiwaju - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 16 May 2026

Ìṣòro àìfọkàntán, àkóyawọ́ àtàwọn mí-ìn lẹ́ka ìdarí nínú ẹgbẹ́ Gomina Onitẹsiwaju

Ibanilorukọjẹ, sisọ ọrọ to le ba ni lọkan jẹ ati gbogbo ariwo lẹka iroyin ko le rọpo akoyawọ ati iduroṣinṣin lori otitọ laelae.
Bẹẹ ni ko si iye irọ funfun to le pa ai ṣe ododo lori awọn nnkan ilu ti wọn fi si ipamọ rẹ, Gomina Hope Uzodinma, rẹ́.
Ọrọ to wa niwaju awọn ọmọ Naijiria atawọn ọmọ ẹgbẹ Gomina Onitẹsiwaju ko ruju rara:  owo ti wọn fi pamọ si ọ lọwọ bii adari fun ajọlo gbogbo ẹgbẹ ni wọn ni o ko le ṣe iṣiro rẹ bayii.

Eyi ki i ṣe idojusọni. Ki i ṣe ti ọdalẹ. Ki i ṣe ogun jija pẹlu. Ibeere fun akoyawọ latọdọ olori fun ohun ti a ni ko ṣọ́ ni.

Ẹgbẹ awọn Gomina kii ṣe eyi ti wọn da silẹ nipasẹ ofin, ẹgbẹ oloṣelu ti wọn tikarawọn da silẹ ni, pẹlu igbagbọ ati Igbẹkẹle laarin awọn gomina ki wọn le jọ ma ṣe ohun rere papọ.

 Nitori ẹ lo ṣe jẹ pe wọn ko gbọdọ foju lasan awọn ẹsun to jẹ jade niwọngba to jẹ pe Igbẹkẹle ati igbagbọ ni wọn fi bẹrẹ ẹ

Aṣiwaju to ba koju iru awọn ẹsun ti ko yẹ ti wọn ba fi kan an ko yẹ ko yẹ ko wa maa lo iwa awuruju tabi ariwo ti ko lẹsẹ nilẹ pana ẹ mọlẹ.Iru aṣaaju bẹẹ gbọdọ fa sẹyin diẹ lati le jẹ ki idajọ ododo waye.

Ariwo lasan kọ ni wọn fi n ṣe aṣaaju bi ko ṣe apẹẹrẹ rere to ba fi silẹ. Ohun to ba mu ki ikunsinu waye, gẹgẹ bi olori o yẹ ki a fi ọgbọn too ni, ki i ṣe ka maa fi iroyin ayelujara bu akẹgbẹ ti ẹ jọ jẹ gomina .

Ko waa yẹ ko jẹ pe ọfiisi tẹ ẹ di mu wa di eyi ti ẹ fi ma lo aṣilo agbara lori awọn ti ẹ jọ jẹ gomina.

Gẹgẹ bi alaga fawọn Gomina, ẹ gbọdọ nigbẹkẹle ninu oye ati igbagbọ ti wọn ni si yin atawọn nnkan rere, amọ to ba ti di oṣelu ti fẹẹ ma da wahala silẹ,Iṣoro ni yoo jẹ ki atunṣe to waye. Ko wa yẹ ki ẹ sa si abẹ igboorun awọn oniroyin lati maa fi tabuku.

Ki i ṣe iru akoko oṣelu taa wa yii lo yẹ ki iru nnkan bẹẹ waye nibi taa ti gbadura fun iṣọkan alaafia ati ifẹ, fun oṣelu to n bọ lọna.

Ko si ẹgbẹ naa to ni itẹsiwaju nibi ti a ti ṣiro iṣẹ irinju ba di wahala.Bẹẹ ni igun oṣelu ko le duro nibi ti ọtẹ ba ti jọba.

Ki eeyan ni igbẹkele ni opo ti gbogbo awọn oloṣelu duro lee lori, to ba wa di pe ọmọ ẹgbẹ n bẹru ara wọn, ko bojumu rara

Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe wahala to  n waye yii ki i ṣe nipa ti owo bi ko ṣe ainigbagbọ ati igbagbọ, bẹẹ lo tun jẹ boya lilo agbara iroyin lati fi le para wọn lẹnu mọ.

Nigba ti wọn si kọ lati pese awọn ẹri to lẹ wẹ wọn mọ lori iṣẹ irinju ti ẹgbẹ gbe lee lọwọ.

Ko wa yẹ ki wọn sọ ọfiisi alaga gomina di ere ori itage nibi ti awọn awada ti ko nitumọ yoo ti maa waye, Wọn gbọdọ fun un ni ọwọ tọ yẹ.Ṣugbọn o ṣe ni laanu pe wọn ti sọ ọ di ibi ti ko si isọkan.

Awọn akẹgbẹ ẹ ki i ṣe ọta ẹ nitori ti wọn beere iṣẹ irinju ẹ bẹẹ ni wọn ko dalẹ ẹ rara, ohun ti wọn si bẹbẹ fun yii nnkan to le yanju nitubi inubi ni, ko mu ija tabi ogun dani rara.

Gomina Hope Uzodinma, akoko yii pe fun iṣẹ irinju lati jabọ ki i ṣe lati fi ṣere tabi pariwo ti ko mu itumọ dani tabi lo awọn oniroyin tako awọn to beere fun ẹtọ ẹgbẹ wọn.

Aṣaaju ti ko ba mọ ẹtọ ẹ, ti wọn ko nigbẹkẹle ninu rẹ ko si ariwo iroyin to le pa otubantẹ ni gbogbo ẹ.

Onimọ-ẹrọ Tunji Akinlade 
Ni o kọ ọ lati ilu Ilaro

No comments:

Post a Comment

Pages