Iyabọ Ọbasanjọ yari kanlẹ: Emi o fẹẹ nnkan mii in yatọ sipo Gomina. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 11 April 2026

Iyabọ Ọbasanjọ yari kanlẹ: Emi o fẹẹ nnkan mii in yatọ sipo Gomina.

Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ninu ibo ọdun to n bọ,tun ti sọ pe ko si ipo mii in toun fẹẹ ju Gomina to si da oun loju pe tikẹẹti naa yoo tẹ oun lọwọ.

Ilu Abẹokuta ni obinrin naa ti sọrọ yii nibi ipinlẹ oniroyin to waye. O sọ pe ahesọ lasan ni pe bi wọn ba fun nipo mii in yala igbakeji Gomina tabi minisita yoo tẹwọgba.

Sẹnetọ Ọbasanjọ sọ pe irọ to jinna si ootọ , nitori pe ipo Gomina lo wa lori ẹmi oun toun si ti pinnu lati dije, toun nigboya pe wẹrẹ ni Ọlọrun yoo ṣe foun.

O ṣalaye siwaju  pe "Mi o wa dije fun igbakeji Gomina, tabi minisita tabi ipo mi, ti wọn ba fi lọ mi, maa ni rars o, mi o fẹ"

O tun sọ di mi mọ pe oun le da duro funra oun lailo ipasẹ baba oun iyẹn Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ.

Ati pe o da oun loju pe awọn iṣẹ toun ti ṣe yoo sọ nipa oun iru eeyan ti oun jẹ..

O tun sọ pe awọn abẹwo  toun ti ṣe kaakiri ijọba ibilẹ foun lọkanbalẹ pe didun ni ọsan yoo so lati dije, ti tikẹẹti yoo si tẹ oun lọwọ.

O waa pari ọrọ ẹ pe owo oun loun naa lati fi ṣe gbogbo nnkan toun ṣe, nitori oun ṣiṣẹ fun un ni ki i ṣe ti baba oun, nile aye yii aimọye aṣeyọri loun ti ṣe.

No comments:

Post a Comment

Pages