Ọdunaro pa awọn ọta Yayi lẹnu mọ: O ni, o ṣi n dije fun ipo Gomina nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 12 April 2026

Ọdunaro pa awọn ọta Yayi lẹnu mọ: O ni, o ṣi n dije fun ipo Gomina nipinlẹ Ogun

Nitori awọn ọrọ kan to n lọ nigboro pe Sẹnetọ Solomon Adeọla tọpọ mọ si Yayi, to n dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC,ko lọ mp, eyi to ti n ja rainrain, ni bayii, wọn ni ọrọ naa ko ri bẹẹ o ati pe digbi ni oludije ọhun ṣi wa ninu ipinnu ẹ.

Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ olori awọn oṣiṣẹ ati oluranlọwọ nipa iroyin fun ọkunrin to n ṣoju ẹkun Ogun West, nile igbimọ aṣofin apapọ niluu Abuja, lo tan imọlẹ si ọrọ naa lakooko to n kopa lori eto ori redio kan.

O sọ pe bigba tawọn kan fẹẹ ma ṣi ọrọ naa gbọ ni, nitori ko sigba kan Sẹnetọ Yayi sọ pe oun ko dije fun ipo gomina  mọ.

O ṣalaye siwaju pe ọrọ ti Yayi sọ lori awọn to n gbe patako ati posita ẹ jade fun ipo naa iyẹn awọn alatilẹyin ẹ pin si meji, akọkọ o fifi ẹmi imoore han si ifẹ ti wọn ni si oun.

Ẹlẹẹkeji gẹgẹ bi Ọdunaro ṣe wi, o tun fi gba wọn niyanju lati le mọ nnkan ti ofin sọ nipa eto idibo to n bọ.

O sọ pe awọn ti wọn bẹru ki Yayi jade dupo gomina ni wọn bẹrẹ si ni gba ọrọ naa bi ẹni gba igba ọti, ti wọn si tunmọ ẹ lati fi da nnkan ru.

Ọdunaro waa ṣapejuwe Sẹnetọ Yayi gẹgẹ bi oloolufẹ itẹsiwaju, eyi to si ti n ṣe latigba ti Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti bẹrẹ saa ẹlẹẹkeji .

O waa rọ gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ogun, ki wọn ma jẹ kawọn eeyan ko girigiri ba wọn,Yayi ṣi wa lori ipinnu lati dije fun ipo gomina.

No comments:

Post a Comment

Pages