Ipade gbogbogboo ADC: Fẹmi Ṣoluade pada sipo alaga ipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 11 April 2026

Ipade gbogbogboo ADC: Fẹmi Ṣoluade pada sipo alaga ipinlẹ Ogun.


Lonii ọjọ Abamẹta, Satide, ni ẹgbẹ oṣelu Affican  Democratic Congress iyẹn ADC, ti ẹka ipinlẹ Ogun, labẹ alaga apapọ wọn David Mark, ṣe ipade gbogbogboo wọn niluu Abẹokuta.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ipade ọhun lo waye nirọwọ-rọsẹ, ti gbogbo nnkan si lọọ ni alaafia.

Agba oṣelu nni, Ọnarebu Moshood Salvador, lati ipinlẹ Eko, lo ṣe alamojuto ipade ọhun,eyi wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi eyi ti ko mu wahala kankan da ni.

Nibi ipade ọhun ni wọn ti da Ọtunba Fẹmi Ṣoluade pada sipo alaga ẹgbẹ naa.Nigba ti Ọmọọba Babatunde Adedeji si jẹ igbakeji.
Awọn yooku ti wọn tun yan ni Agbebiyi Oluṣọji gẹgẹ bi akọwe atawọn akọwe yooku.

Agbẹjọro Fẹmi Aina, to jẹ oludamọran nipa ofin lo ṣebura fawọn oloye tuntun gẹgẹ bi ilana ati ofin ṣe la a silẹ fun wọn.

A tun gbọ pe  iru ipade bẹẹ tun waye lati awọn kan ti wọn pe ara wọn ni adari, amọ ti wọn ni ayederu ni wọn, eyi ti wọn ṣe ni OOPL.

Wọn ti parọwa pe awọn to ṣe Ipade gbogbogboo yatọ si Fẹmi Ṣoluade to di alaga wọn yii ko tẹle ilana ati ofin,ki ẹnikẹni ma ṣe bawọn ni nnkan ṣe pọ.

Wọn waa ni iṣọkan ni ẹgbẹ ADC ipinlẹ Ogun, pẹlu arọwa pe ki gbogbo awọn to ni ikunsinu gbagbe nnkan to ti ṣẹlẹ ki wọn jẹ ki wọn jọ fọwọsowọpọ gbe ẹgbẹ yii soke.

No comments:

Post a Comment

Pages