Idi ti mo fi fẹẹ ṣayẹyẹ iranti ogun ọdun ti Tọba Ọpalẹyẹ jade laye -Kasnanty Sugar - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 11 April 2026

Idi ti mo fi fẹẹ ṣayẹyẹ iranti ogun ọdun ti Tọba Ọpalẹyẹ jade laye -Kasnanty Sugar

Gbajumọ sọrọsọrọ ti irawọ ẹ tan kaakiri Kọlawọle Adejojo tọpọ awọn eeyan mọ si Kasnanty Sugar, ti ṣalaye idi to fi fẹẹ ṣayẹyẹ ogun ọdun ti agba sọrọsọrọ nni Tọba Ọpalẹyẹ jade laye, eyi ti yoo waye lọjọ kin in ni, oṣu karun-un, ọdun yii ni Continental Suite, Ibara, Abẹokuta.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni bi a ba ranti awọn to wa laye bẹẹ lo yẹ ki wọn maa ranti awọn to ti lọ nitori ipa ti wọn ti ko.

O sọ pe bi oun ba wo daadaa pẹlu ilana Oloogbe Tọba Ọpalẹyẹ lo jẹ ki oun di ẹni to n sọrọ lori redio lonii bẹẹ lo si jẹ pe ọmọ to kọ niṣẹ iyẹn Yẹmi Ṣonde ni ọga toun.

Kasnanty tun fikun ọrọ ẹ pe 'Ilana Tọba Ọpalẹyẹ ni mo si n tọ nipasẹ Yẹmi Ṣonde, gbogbo igba to fi n ṣeto idaji wakati ni mo ti fẹran ẹ daadaa, nigba to si tun wa jẹ pẹ ọmọ ẹ to kọọ niṣẹ, Sonde lo kọ emi, ki lo wa buru ju nibẹ, ti mo ba ṣeranti iru ẹni bẹẹ"

Ọkunrin to tun ni imọ nipa ọgbọn atinuda yii tun sọ pe awọn tun ṣeto ọhun lati jẹ kawọn eeyan ranti awọn iṣẹ to ti ṣe, iru eeyan to jẹ nigba to wa laye ati nnkan ti wọn ṣi ranti nipa ẹ titi di akoko yii.

O tun ṣalaye siwaju pe lọjọ oniwaasi nni Sheik Yah Satar, ni yoo gba wọb niyanju lọjọ naa.

Kasnaty tun fikun un pe awọn yoo tun ṣagbeyẹwọ awọn orin ẹ.O ni aye yoo wa fawọn eeyan lati sọ nipa awọn iṣẹ Oloogbe naa to ti ṣe ti wọn fẹran lati maa gbọ di akoko yii.

O ni lọjọ naa lawọn yoo ṣafihan idile Tọba Ọpalẹyẹ fawọn eeyan tawọn yoo si beere iha tawọn eeyan kọ si wọn latigba ti ilu mọn ọn ka naa ti jade laye.

Lara awọn to pe lọjọ naa ni ọga ẹ, Yẹmi Ṣonde, awọn oloolufẹ Tọba Ọpalẹyẹ , Wessy, oludari ati alaṣẹ Continental Suite atawọn eeyan pataki lawujọ.

No comments:

Post a Comment

Pages