Irinajo Tinubu nipinlẹ Ogun lọjọ Satide to n bọ apẹẹrẹ idagbasoke nla lo jẹ-GNI - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 1 April 2026

Irinajo Tinubu nipinlẹ Ogun lọjọ Satide to n bọ apẹẹrẹ idagbasoke nla lo jẹ-GNI

Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, to n ṣoju ẹkun Imẹkọ Afọn/Yewa North niluu Abuja, ti ṣapejuwe irinajo Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu si ipinlẹ Ogun, lọjọ Abamẹta,Satide, gẹgẹ bi eyi ti yoo to mu idaniloju ipa tijọba apapọ n ko fun idagbasoke.

Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Fẹmi Peters, to jẹ akọwe iroyin ẹ fi sita lo ti n ki Aarẹ Tinubu kaabọ si ipinlẹ Ogun fun iṣẹ akanṣe pataki to fẹẹ waa ṣe naa.

Ọnarebu Isiaka to tun dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ninu ibo ọdun 2027, ṣalaye pe abẹwo aarẹ ọhun tun fihan igbagbọ  to ninu isakoso ọrọ aje ati erongba atunṣe.

O ṣakiyesi pe awọn ọmọ orileede yii ti bẹrẹ si n ri ayipada latari awọn idojukọ wọn tẹlẹ.

O sọ pe bi ipinlẹ Ogun ṣe jẹ gẹgẹ bi aarin gbungbun ọkoowo ati ọrọ ajè jẹ ki ajọṣepọ to danmọran wa laaarin wọn ati ijọba apapọ.

Gboyega Nasir Isiaka tun sọ pe" Aarẹ wa, inu mi dun lati ki yin kaabọ, o da mi loju pe irinajo ayọ ni irinajo yin jẹ fun gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ogun, eyi ti yoo si mu idaniloju wa fun ọkẹ aimoye awọn ọmọ orileede yii ti wọn wo awọn iṣẹ tẹ ẹ n ṣe ni eyi to mu da ireti pada pe nnkan yoo ṣẹnure".

Bẹẹ ni GNI tun ṣakiyesi pe lakooko ijọba Dapọ Abiọdun to n lọ lọwọ yii aimọye idagbasoke lo ti mu ba ipinlẹ naa labẹ erongba aarẹ lati da ireti pada fawọn araalu to ra wọle.

O waa ṣapejuwe ajọṣepọ to danmọran laarin ipinlẹ Ogun ati ijọba apapọ, eyi to n jẹ ki aṣeyọri nla mu itẹsiwaju ba wọ

No comments:

Post a Comment

Pages