Ọrọ iwuri yii waye lakooko ti oludije naa ṣabẹwo lọọ ki wọọn t si tn lo anfaani ọhun lati ṣe ipade pọ pẹlu wọn nipa erongba ẹ lati dije.
Ninu ọrọ tawọn ọmọ ẹgbẹ naa sọ ni wọn ti ṣeleri pe gbogbo atilẹyin to ba tọ, to si yẹ lawọn yoo ṣe fun oludije naa nitori awọn mọ pe o ka ipa ẹ.
Bẹẹ ni wọn tun gba niyanju lati rii pe ko ma fawọn agba ẹgbẹ atawọn olori wọn ti wọn wa niluu Abuja silẹ ki erongba ẹ ko le wa si imuṣẹ.
Ọpọ awọn to tun sọrọ naa ni wọn tun sọrọ ni wọn mẹnuba awọn anfaani tawọn ri latọdọ obinrin naa lakooko to fi jẹ kọmiṣanna feto ilera ati ajọ Iyaniwura to daa silẹ
Wọn waa gba nimọran lati ma ṣẹ rẹwẹsi ọkan lori erongba to wa niwaju ẹ yii.
Nnu ọrọ Sẹnetọ Ọbasanjọ o fi idunnu ẹ han lori bawọn ara Odogbolu ṣe waa fi ijo ati ayọ pade re.
O sọ pe oun yoo tubọ tẹsiwaju lati mu idagbasoke ba awọn eeyan igberiko ati pe oun ko nii kaarẹ lati rii pe awọn eeyan n gbe igbe aye to dẹrun.
No comments:
Post a Comment