Ninu atẹjade kan ti Zakari Chado, agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun fi sita, o sọ pe laaarin ọjọ kọkandinlogun si kẹrinlelogun, oṣu kẹta, lawọn ri kinni ọhun gba lọwọ wọn.
O sọ pe aṣeyọri nla ni bi wọn ṣe rawọn kẹẹgi epo naa gba jẹ fun eto ọrọ aje wa. O tun sọ pe eyi tun ṣafihan bi ọga wọn nipinlẹ Ogun, ko ṣe gba ojubọrọ fawọn ti wọn fi fayawọ ba nnkan jẹ nipinlẹ naa
Agbẹnusọ awọn aṣọbode tun fikun ninu ọrọ ẹ pe lati le jẹ kawọn araalu mọ pe ileeẹsẹ wọn atawọn alaabo ilu jọ n ṣiṣẹ pọ, o ni awọn ti fa tirọọki tawọn okuta tawọn kan lọọ ji wa le ileeṣẹ to n ri si ọrọ alumọni lọwọ.
O sọ pe ilu Abẹokuta ni eto fifa okuta ọhun ti waye. Nigba to n fa a kalẹ, ọkan lara awọn ọga aṣọbode, E K Onyeasor to ṣoju ọga agba wọn,O O Afẹni ṣalaye pe bi wọn ṣe n ṣowo aiyederu awọn okuta alumọni jẹ akoba nla fun ọrọ aje wa.
O sọ pe ileeṣẹ aṣọbode toun si jẹ adari wọn lakooko yii nipinlẹ Ogun ko nii foju awọn to le fẹẹ ma ba ohun alumọni wa a jẹ.
Ninu ọrọ Abimbọla Olubunmi nigba to n tẹwọ gba lo ti dupẹ lọwọ awọn aṣọbode fawọn iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati rẹyin awọn onifayawọ jakejado.
No comments:
Post a Comment