Sẹnetọ Ọlamilekan Yayi ṣajọyọ ọjọọbi pẹlu Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 29 March 2026

Sẹnetọ Ọlamilekan Yayi ṣajọyọ ọjọọbi pẹlu Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu

Ṣẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla, to n ṣoju ẹkun Ogun West, nile igbimọ aṣofin agba, niluu Abuja, to tun jẹ oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ti fi idunnu ẹ han lori ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣe lonii.

Ninu atẹjade ti agba oṣelu naa fi sita lo ti ṣapejuwe Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bi baba, ọga, alawokọṣe ati adari rere.

O sọ pe Aarẹ Tinubu jẹ ẹni ti igbe aye ẹ jẹ ẹni to ni igboya to duro gbọingbọin, to si ni afojusun ọjọ iwaju,ti ọgbọn gbilẹ, eyi to fi n ṣakoso orileede yii.

Sẹnetọ Yayi tun ṣalaye siwaju pe idari Aarẹ ko duro lori eto ọrọ ajẹ to ti mẹhẹ ko to gbakoso bi ko ṣe pe o tun ṣe igbe dide ati itọni ọpọ awọn eeyan ti wọn ti jẹ anfaani ninu ọgbọn ẹ.

O ni titi di akoko yii opo ilọsiwaju nidii oṣelu ni Tinubu pẹlu awọn ilakaka ẹ, ti orukọ ẹ ko si ni parẹ ninu itan orileede yii.

Yayi waa gbadura pe ki Ọlọrun tubọ fun ni ẹmi gungun, alaafia ati ilera to peye, eyi ti yoo fi dari wa ninu erongba ireti atunṣe to dawọ le

No comments:

Post a Comment

Pages