Aṣaaju rere ti ko ni afiwe ni Aarẹ Bọla Tinubu- Gboyega Nasir Isiaka - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 29 March 2026

Aṣaaju rere ti ko ni afiwe ni Aarẹ Bọla Tinubu- Gboyega Nasir Isiaka

Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, to n ṣoju ẹkun Imẹkọ Afọn/Yewa North nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja,to tun dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo to n bọ lọdun 2027,  ti ṣapejuwe aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, gẹgẹ bi akọni eeyan, aṣaaju rere ti ko ṣe lafiiwe lawujọ fawọn ipa manigbagbe to ti ko.

Ninu atẹjade kan to fi sita lati fi sapọnle Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fun ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin ti Aṣiwaju ṣe lonii.

O tun ṣapuwe Aarẹ naa gẹgẹ bi adari rere to figba gbogbo ṣafihan awọn iran ati igboya to ni ki orileede yii le gunlẹ si ebute ire.

Gboyega Isiaka tun fikun ninu ọrọ ẹ latigba ti aarẹ Tinubu ti dori aleefa pẹlu ikoju ọpọ ipenija,ṣugbọn o fi igboya to ni ati erongba ẹ lori ireti atunṣe lati da iṣejọba orileede yii pada.

O waa bujuwo itan igbesi aye Tinubu latilẹ, GNI, o ni akikanju ati akọni ni bi a ba sọrọ nipa ijọba dẹmokireesi fawọn ipa to ti ko sẹyin paapaa nigba to jẹ gomina ipinlẹ Eko, nibi to ti kọkọ ṣe atunṣe rere iṣejọba fawọn araalu, eyi ti ko si gbẹyin lakooko yii to jẹ aarẹ orileede.

GNI waa ki aarẹ Tinubu- lorukọ ẹbi ẹ, atawọn eeyan agbegbe to n ṣoju nile igbimọ aṣoju ṣofin niluu Abuja fun ti ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin pẹlu adura pe yoo ṣe ọpọ ọdun ninu alaafia to pe ati ẹmi gungun .

No comments:

Post a Comment

Pages