Tunde Lẹmọ ba Aarẹ Tinubu ṣajọyọ ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin lori eepẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 29 March 2026

Tunde Lẹmọ ba Aarẹ Tinubu ṣajọyọ ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin lori eepẹ

Tunde Lẹmọ, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC,nipinlẹ Ogun ti ba aarẹ orileede yii Aṣiwaju Bọla Ahmed ku ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin lori eepẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba banki ilẹ wa fọwọ si lo ti ṣapejuwe Aarẹ Tinubu gẹgẹ bi aṣaaju to ni imọ ọjọ iwaju ati igboya to nigbagbọ fun ọjọ rere orileede.

O ṣalaye awọn ipa ti Tinubu ti ko ninu iṣejọba ati idagbasoke orileede yii, o ni ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin ẹ yii  ti ṣami pataki oṣelu ẹ fun idagbasoke awọn eeyan ati ipa ẹ.

Tunde Lẹmọ tun fikun ọrọ ẹ pe nipa erongba aarẹ lori to n lọ lọwọ eyi to pe ni "Ireti Atunṣe" eyi to fi atilẹyin ọjọ iwaju iran to n bọ dara.

O waa ṣapejuwe ọna ti Tinubu gba ṣejọba rẹ, eyi to nigbagbọ pe yoo mu idẹrun bawọn ọmọ orileede yii. O gbadura fun aarẹ pe ki Ọlọrun tunbọ lọra ẹmi wọn.


No comments:

Post a Comment

Pages