Aṣaaju ni Tinubu nipa adari, imayedẹrun ati eto abo-Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 29 March 2026

Aṣaaju ni Tinubu nipa adari, imayedẹrun ati eto abo-Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ

Oludije fun ipo Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo to n bọ lọna, Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ti gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, gẹgẹ bi adari tootọ, to ṣe fọkan sin lori awọn iṣejọba fun imayedẹrun ati abo, eyi to sọ pe o gbinyanju pupọ.

O sọrọ yii nibi atẹjade to fi ki Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ku oriire ọjọọbi ọdun kẹrinlelaadọrin, to n ṣe lonii.

Obinrin naa sọ pe awọn ipa pataki ti ọlọọjọbi naa ti ko fun idagbasoke orileede yii jẹ anfaani nla, ti ko ṣe gbagbe.

Iyabọ Ọbasanjọ tun ṣalaye siwaju pe " Eto isakoso yin labẹ erongba ireti atunṣe,eyi to n tẹsiwaju ti mu ki nnkan goke si nipasẹ ọrọ aje atawọn nnkan mii.

"Emi funra mi gan-an gboriyin fun yin fawọn erongba yin nipa awọn atunṣe ọna to jẹ tijọba apapọ lorile ede yii ati tipinlẹ Ogun, ti mo ti wa".

Bakan naa ni Ọbasanjọ tun gboṣuba o kare fun Tinubu lori awọn ilakaka ẹ  nipa eto abo jakejado orileede yii.

Bẹẹ lo tun kii ku aṣeyọri ti ipade gbogbogboo ẹgbẹ APC, ti wọn ṣẹṣẹ pari, eyi to sọ pe o pari pẹlu ayọ ati alaafia.

O waa fi adura pari ẹ pe ki Ọlọrun tubọ lọra ẹmi wọn ninu alaafia pipe ati ifọkanbalẹ,ki o si fun ni ọgbọn ati oye ti yoo fi jẹ ki orileede yii gbilẹ ninu isọkan .

No comments:

Post a Comment

Pages