Iyabọ Ọbasanjọ ṣe bẹbẹ nibi ayẹyẹ ọjọọbi Iyabọ Aniṣulowo niluu Ilaro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 21 March 2026

Iyabọ Ọbasanjọ ṣe bẹbẹ nibi ayẹyẹ ọjọọbi Iyabọ Aniṣulowo niluu Ilaro


 Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ awọn eeyan nibi ayẹyẹ ọjọọbi ọdun marundinlọgọrin Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo to waye niluu Ilaro lonii, ọjọ Abamẹta, Satide,nitori bi ọkan lara awọn oludije gomina, Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, ṣe ṣe bẹbẹ jọjọ naa.

Idi abajọ ni pe bi obinrin to n dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, ṣe debẹ ni ariwo gba ibi ti ayẹyẹ naa ti waye.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC fọdun 2027  ni wọn wa nibẹ, o fẹẹ jẹ pe ariwo obinrin naa lo fẹẹ pọju lọjọ naa.

Bi Iyabọ Ọbasanjọ ṣe de ọhun pẹlu ẹrin ati ọyaya lo fi n ki awọn eeyan paapaa awọn ti fẹẹ jọ dupo gomina, ko to di pe o pada lọ jokoo si ijokoo ti wọn ti pese silẹ fun.un.

Iyabọ Aniṣulowo, ẹni to ti figba kan jẹ minisita feto ẹkọ, bẹẹ loun ni obinrin akọkọ to jẹ sẹnetọ lati ẹkun Ogun West, lo pe awọn eeyan jọ lati wa baa ṣajọyọ ayẹyẹ ọọọbi ọdun karundinlọgọrin 

Nigba to ṣapejuwe ọlọjọọbi naa, Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi aṣaaju rere ti wọn ti fi akọsilẹ rere silẹ.

O ni obinrin ọhun jẹ onigboya ti ko bẹru lati sotitọ nibi to ba yẹ, to si tun ẹni ti ko gba iwọsi laye, to si maa n fẹ ki awọn obirin akẹgbẹ ẹgbẹ wa nipo aṣiwaju.

O waa gbadura pe ki Ọlọrun tunbọ lọra ẹmi wọn pẹlu alaafia.

No comments:

Post a Comment

Pages