Oṣelu ẹlẹyamẹya ko le mu ilọsiwaju ba ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii- Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 21 March 2026

Oṣelu ẹlẹyamẹya ko le mu ilọsiwaju ba ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii- Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi

Lati le jẹ ki mundunmudun ijọba dẹmokireesi ta a n lo lọ lorileede yii le jẹ itẹwọgba bi a ṣe n fẹ,Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludasilẹ ẹgbẹ to n ri si ọna abayọ iyẹn The Alternative, ti rọ gbogbo awọn ẹlẹgbẹ oṣelu lati yẹra nipa ẹlẹyamẹya, ki wọn sun siwaju fun iṣọkan.

Agba oṣelu yii sọrọ naa lakooko to n kopa lori eto ori redio Splash FM,lọjọ Ẹti, Furaide ọsẹ yii.

O ṣalaye siwaju pe lojumọ to mọ lonii ẹgbẹ oṣelu APC,PDP ati Labour, lo lero to pọju lorileede yii, o waa rọ wọn lati ma ṣe jẹ ki wọn fi imọtara ẹni nikan wọn ṣakoba fun eto oṣelu wa.

Ọdọfin Kemta ilẹ Ẹgba wsa pe fun iparapọ ẹgbẹ oṣelu ki wọn lọọ forukọ silẹ, ki wọn si ẹka to peye eyi ti yoo erongba rere lọkan.

Bẹẹ lo n tẹnumọ oṣelu ẹlẹyamẹya tawọn kan n rawọle lorileede yii, eyi to nigbagbọ pe o fẹẹ maa ṣakoba eto iṣejọba orileede yii.

O sọ pe ohun to dara ki awọn aṣaaju lorile ede yii gba isọkan laaye.O ni a gbọdọ jẹ ki Naijiria wa ni isọkan laifi ti ẹlẹyamẹya ṣe. O ni o dara ki a pin orileede yii si wẹwẹ kawọn to ni ihuwasi ẹlẹyamẹya le ṣe nnkan to wu wọn lọkan.

No comments:

Post a Comment

Pages