Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, idi abẹwo wọn ni lati ṣepade pọ pẹlu Sẹnetọ Iyabp Ọbasanjọ, toun naa jẹ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Ẹgba, lori erongba ẹ fun oludije gomina.
Ninu ọrọ Oloye Mustapha Owolabi, to jẹ alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, o sọ pe abẹwo yii ṣe pataki, nitori pe idunnu lo jẹ fawọn pe Sẹnetọ Ọbasanjọ jade, eyi to mu iwuri waa pe obinrin le jade lati ilẹ Ẹgba lati dije fun ipo gomina.
O ṣalaye pe odu ni Iyabọ Ọbasanjọ ki i ṣe aimọ foloko wọn, nitori awọn ipa to ti ko sẹyin lakooko to dipo kọmoṣanna feto ilera mu ati igba to fi jẹ sẹnetọ fun ẹkun aarin gbungbun, iyẹn Ogun Central.
Oloye Owolabi tun tẹnumọ ọn ninu ọrọ ẹ pe ilẹ Ẹgba ti n gbaradi bẹẹ ni wọn ti wa nimurasilẹ lati fa ọmọ wọn silẹ fun ipo gomina ọhun, nitori ile ni a ti n ko ẹṣọ rode, gẹgẹ bi ọrọ Yoruba.
Nigba to n fesi, Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ fi idunnu ẹ han si Ẹgba Agenda Forun fun abẹwo ti wọn ṣe si ọdọ oun.
O sọ pe eyi tun jẹ iwuri nla foun lati le sin awọn eeyan oun gẹgẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ Bẹẹ lo mu dawọn loju pe oun ko nii figba kankn doju ti wọn ti eto iṣejọba oun yoo rọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lọrun.
No comments:
Post a Comment