Biyi Ọtẹgbẹyẹ ki Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo ku oriire ọjọọbi ọdun karundinlọgọrin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 22 March 2026

Biyi Ọtẹgbẹyẹ ki Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo ku oriire ọjọọbi ọdun karundinlọgọrin


Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC,lọdun 2023, ti ba Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo, ẹni to ti figba kan jẹm minisitaó feto ẹkọ, ṣajọyọ ayẹyẹ ọjọọbi ọdun karundinlọgọrin to waye lana an niluu Ilaro.

Ọtẹgbẹyẹ toun naa wa nibi ayẹyẹ ọjọọbi ọhun lo ti ṣapejuwe Iyabọ Aniṣulowo gẹgẹ bi mama rere to maa n ṣatilẹyin fun ọmọ, to si tun fẹran rere fawọn to ba yii kaakiri.

O sọ pe ninu oṣelu Mama Aniṣulowo ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin fawọn ipa to ti ko nipinlẹ Ogun paapaa julọ ilẹ Yewa.

O ni bi wọn ba sọrọ nipa eto ẹkọ Aniṣulowo saa gbogbo agbara ẹ lati rii ilọsiwaju deba eto ẹkọ lorileede yii, o ni ki a ma ṣe gbagbe pe iṣẹ tiṣa ni wọn fi bẹrẹ.

Biyi Ọtẹgbẹyẹ tun mẹnuba  bi Mama Aniṣulowo ṣe duro tii lọdun 2023, nigba to jade dupo gomina.

O ni erongba mama naa ni ki Yewa di gomina nipinlẹ Ogun, eyi toun gbadura  pe yoo wa si imuṣẹ lakooko Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo.

O waa gbadura pe ki Ọlọrun tunbọ fun Mama ni ẹmi gungun ati alaafia.

No comments:

Post a Comment

Pages