Nibi ayẹyẹ ọhun gbooro to, ilu Ilaro naa mọ pe oun gbalejo awọn eeyan pataki lawujọ lorileede yii ati ni oke okun ti wọn waa ba ẹni to ti figba kan jẹ minisita feto ẹkọ lorileede yii ṣajọyọ.
Bi inu ẹni ba dun ki i pa mọra bẹẹ lọrọ ri fun ọlọjọọbi naa nigba to kọkọ lọ ṣe idupẹ ni ṣọọṣi nibi tawọn eeyan pataki to fi mọ awọn oloṣelu ti wa baa yin Ọlọrun fun idasi ẹ latigba to ti dele aye.
Aniṣulowo to jẹ sẹnetọ obinrin akọkọ nipinlẹ Ogun, ko fi para rara nigba ti orin ọpẹ bẹrẹ si nii jade lẹnu ẹ, nigba to ro gbogbo awọn ewu to tii la kọja titi di akoko yii.
Lẹyin ti wọn kuro nibẹ ni wọn gba ile itura Frontier to wa niluu Ilaro lọ, nibi ti wọn ti ṣefilọlẹ iwe ti Sẹnetọ Aniṣulowo kọ lati fi sami ọjọọbi ẹ.
Iwe ọhun to kọ ni ede oyinbo lo pe akọle ẹ ni "My story of Grace and Grit" nibi to to ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa irinajo igbe aye atawọn nnkan to foju winna papa nipa oṣelu.
Ohun to tun jẹ ki ayẹyẹ naa tun larinrin ni pe ṣe lọpọ awọn oloṣelu ti wọn fẹẹ dije fun ipo gomina lọdun 2027, wa yẹ mama naa si.
Lara wọn ni Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla Yayi, to n ṣoju ẹkun Ogun West, niluu Abuja, Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, to n ṣoju ẹkun Imẹkọ Afọn, nile igbimọ aṣoju ṣofin, Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, Mọdele Ṣarafa Yusuf, Ọnarebu Ladi Adebutu.
Bakan naa igbakeji Gomina nipinlẹ Ogun, Nọimọt Salakọ Oyedele naa wa nibẹ,Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun,Sẹnetọ Ibikunle Amosun naa ko gbẹyin atawọn eeyan pataki mii lawujọ .
No comments:
Post a Comment