Ipade ọhun to waye ni afin Awujalẹ lawọn ọba alade mẹrindinlọgọta ni gbogbo ilẹ Ijẹbu ti peju pesẹ.
Wọn tiẹ ni obinrin naa ni ẹni akọkọ ninu awọn oludije ti yoo jọju sawọn ọba ilẹ Ijẹbu latigba tawọn ti ariwo awọn oludije kaakiri.
Ọba Lawrence Jaiyeọba Adebanjọ, to jẹ alaga awọn ọba alade, lẹyin to ṣadura fun un tan lo rọ lati ma fa sẹyin lori erongba ọjọ iwaju ẹ yii.
Bẹẹ lo tun gboriyin fun fawọn ilakaka ẹ lati di gomina eyi to sọ pe oun nigbagbọ pe yoo so eṣo rere.
Ọba naa wa ṣapejuwe awọn ipa to lapẹẹrẹ ti Sẹnatọ Iyabọ Ọbasanjọ ti ko, eyi to ni awọn akọsilẹ ẹ ti wa nilẹ,to si ṣe tọka si titi di akoko yii.
Lara awọn ọba alade ti wọn tun wa nibẹ lọjọ naa ni Ọba Anthony Alakija, Ọba Sikiru Okuribido ari Ebumawe tiluu Agọ Iwoye, Ọba Abdulrasaq Adenugba.
Lẹyin ti Ṣẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ṣe ipade pọ pẹlu wọn bẹẹ lo tun ṣe ipade idankọkọ, eyi ta a lero pe o yọri si rere.
No comments:
Post a Comment