Liṣabi: Irinajo awọn ara Ẹgba ati titẹ Ilu Abẹokuta do - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 25 March 2026

Liṣabi: Irinajo awọn ara Ẹgba ati titẹ Ilu Abẹokuta do



Bi a ba n sọrọ nipa itan Ẹgba, itan to lagbara ni, ti ko yẹ ki irandiran gbagbe lailai. Bo tilẹ jẹ pe gbogbo ilakọja wọn ko rọrun rara ṣugbọn ti ipari ẹ yọri si ayọ, isọkan ati alaafia.

Ko si bi wọn ṣe le mẹnuba itan, ati bi irinajo Ẹgba ṣe bẹrẹ ki a maa darukọ Liṣabi Agbongbo Akala, ẹni to mu ayanmọ ati kadara awọn eeyan ẹ yipada si rere iyẹn lọdun 1760.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bi ọdun ẹẹtadinlogun ṣẹyin abẹ Ọyọ ti wọn pe ni Oyo Empire ni Ẹgba ti n gba aṣẹ.

Aye fami lete ki n tutọ lawọn ara Ọyọ fawọn Ẹgba jẹ, ni gbogbo akoko ta a n sọrọ ẹ yii, ti wọn ko si gbọdọ pariwo sita, iso inu ẹku ni wọn n fi ọrọ ọhun ṣe laarin ara wọn.

Ko si ilẹ awọn Ẹgba nigba naa ti wọn ko jẹ gaaba le lori. Nigba ti yoo si fi di ọdun 1760, nnkan ti bẹrẹ si ni n yipada, eyi to pada waa di itan lonii.

Itan fi ye wa pe iṣẹ jagunjagun nikan kọ ni a mọ mọ Liṣabi,Ọlọrun tun fun un lẹbun ọgbọn atinuda.Gbogbo ero inu ẹ ni pe ko si nnkan ti eeyan ba fẹẹ ṣe laye, isọkan ni wọn gbọdọ fi bẹrẹ ko le ba a ni aṣeyọri.

Idi niyii to fi ko awọn eeyan jọ lati maa ṣe àáró fun iṣẹ agbẹ lati maa ba ara wọn ro oko.
Labẹ aaro agbẹ ti wọn ṣe laarin ara wọn yii, ni ifọwọsowọpọ ti bẹrẹ, ti wọn si n nigbagbọ ninu ara wọn, pẹlu erongba kan naa laaarin awọn Ẹgba.

Ko si pẹ tawọn Ẹgba fi n gbena woju awọn alaṣẹ Ọyọ nigba naa ti wọn si n gba ara wọn kalẹ diẹdiẹ lati sọ ara wọn di ominira.

Liṣabi ko fẹẹ ki iya tawọn Ọyọ fi n jẹ Ẹgba latọjọ pipẹ wa tunbọ tẹsiwaju, to fi gbe igbesẹ igbara ẹni silẹ lọwọ oko ẹru awọn eeyan naa.

Gbogbo nnkan to yẹ lo fara ẹ silẹ lati ṣe, loootọ ko rọrun lati gba agbara ti wọn fi mu wọn sin yii,  eyi to mu kawọn Ẹgba igba naa fọnka kaakiri.

Fun bi ọpọ ọdun sẹyin lawọn Ẹgba igba naa kuro nibi ti wọn wa ti wọn si ibi ti wọn le farapamọ si fun aabo. Pẹlu gbogbo idojukọ ti wọn ba pade bi wọn yoo ṣe di ominira lo jẹ Liṣabi logun.

Bẹẹ ni wọn ko fi ara wọn silẹ ti wọn si n gbe inu irẹpọ.Ohun gbogbo ti wọn n ṣe ni wọn gba itọsọna lati ọdọ ifa, eyi ti wọn ni Ọrunmila ti sọ pe oun ti pese ibudo kan silẹ nibi ti wọn yoo tẹdo si ti alaafia ati irọrun yoo ti de ba wọn.Awọn eyi to ku si ti di itan bayii.

Nigba to di ọdun 19 century, irinajo ọlọdun gbọgbọrọ jẹ ki wọn tẹdo si Abẹokuta, eyi ti wọn ri gẹgẹ bi idaboobo paapaa julọ ori oke olumọ, Abẹokuta yii wa gba gbogbo Ẹgba fun aabo nla.

Nitori bi wahala ṣe kọkọ pin awọn eeyan ilẹ Ẹgba tẹlẹ,wọn waa pada di igun, ti ko pariwo, to si n gbeja ara wọn ja pẹlu ilepa ọjọ iwaju.

Lonii, a n ranti awọn irinajo naa nipa ajọyọ ṣiṣe afihan aṣa wa bii ayẹyẹ ọdun Liṣabi.Ohun to ṣe pataki ni ẹkọ nla ni itan Liṣabi ati Ẹgba jẹ lati ni iforiti paapaa awọn iran to n bọ, bẹẹ lo tun jẹ ka ni ero ajumọṣe,ipa to wa ninu iwoye ọjọ pipẹ.

O ṣe e ṣe ki Liṣabi maa ri Abẹokuta, ko ma ri isọkan ati ilọsiwaju to le mu jade,amọ igboya ẹ to ni 1760, lo jẹ ka maa sọ itan rere nipa ẹ.

Lakotan, bi wọn ṣe da Abẹokuta silẹ  ki i ṣe itan bi wọn ṣẹ tẹ ẹ do ati pe akọni Liṣabi, ki i ṣe aṣeyọri to ṣe bi ko ṣe bo ṣe bẹrẹ.

Bi a ṣe wa n ṣajọyọ ọdun kọkandinlogoji ọdun Liṣabi, mo rọ yin lati gbe iru ẹmi ti Liṣabi sọkan yoo si ran wa lọwọ lati gbe ogo ilẹ wa ga.

Lisabi Agbewa oooo!

Oloye Mustapha Abdulhakeem O.
Akinfiwatolu  tilẹ Ẹgba

No comments:

Post a Comment

Pages