Aṣiri awọn to n ko ayederu epo bẹntiroolu lọna aitọ ti tu sọwọ awọn asọbode - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 14 June 2024

Aṣiri awọn to n ko ayederu epo bẹntiroolu lọna aitọ ti tu sọwọ awọn asọbode 

Lati le fopin si gbigbe epo bẹntiroolu wọlu lọna aitọ, ajọ aṣobode ti sọ pe ẹgbẹrun mẹtalelogun ati ẹẹdẹgbẹrun le mẹẹdọgbọn lita ayederu yii, eyi towo ẹ to miliọnu mẹtala naira lawọn ti ri gba laarin ọsẹ meji.

 

Hussien Kẹhinde Ejibunu, to jẹ alakoso fun igbimọ iṣẹ akanṣe labẹ ajọ naa lo kede ọrọ yii lakooko to n ba oniroyin sọrọ niluu Abẹokuta nipa awọn aṣeyọri ti wọn ti ṣe lẹnu ọsẹ meji ti wọn bẹrẹ iṣẹ ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe wi awọn ero bẹntiroolu yii lawọn fayawọ kan n gbe jade kuro lorileede yii ko to di pe ọwọ tẹ wọn pẹlu awọn tirela ti wọn fẹẹ fi ko o jade, bẹẹ lo sọ pe awọn ti ti ileepo ti wọn ti n ta yii pa pẹlu.

Lara awọn ibi ti ọga agba aṣọbode ọhun sọ pe awọn ti rawọn ayederu bẹntiroolu ọhun ati ileeṣẹ wọn nipinlẹ Ogun ni SEAYAB PETROLEUM, to wa lọna Imẹko/Ọbada, QUAWIYAN RESOURCE PETROLEUM NIG. LTD, toun wa lọna Owode/Atan , ati JULANKY DIL & GAS, lọna  Owode/Ilaro.

Ko to to akoko yii ni ọga awọn aṣọbode pata lorileede yii, Bashir Adewale Adeniyi, ti kọkọ kede pe ẹgbẹrun lọna ọrinlenigba ati aarun din logoje lita,( 280,135) eyi towo ẹ fẹẹ to miliọnu lọna igba naira, ayederu epo bẹntiroolu yii lawọn ri gba kaakiri orileede yii.

Ejibunu tun fikun ninu ọrọ ẹ pe lara nnkan tawọn ri gba ni tirọọki nla ti agba epo mẹtadinlọgọrin ni wọn ri gba nile epo SEAYAB PETROLEUM , lọna  Imẹko /Ọbada, nipinlẹ Ogun, iyẹn lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ keje, oṣu kẹfa, ọdun yii. O ni dẹrẹba to wa ọkọ naa wa larọwọto wọn.

Bakan naa lo tun ṣalaye pe ọgọrun ike oni lita mẹẹdọgbọn, ti epo yii wa ninu ẹ lawọn ri nileepo Quayam Resource Petroleun, along Owode / Atan road in Ogun nipinlẹ Ogun, inu mọto Toyota Kamri, ti nọmba ẹ jẹ 4TIBE3KXU672540, iyẹn lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu yii.

 

Bẹẹ lo ni ike epo bẹntiroolu ogoje o le ẹyọ kan lita lawọn ri nileepo JULANKY OIL & GAS , lọna Owode /llaro, lọjọ Satide, ọjọ kọjọ, oṣu yii bakan naa. Ọga agba naa wa kilọ fawọn to ni tirọọki ti wọn maa n lo lati fi ṣe okoowo fayawọ yii pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo ru igi oyin.

No comments:

Post a Comment

Pages