Ẹgbẹ oṣelu ADC ipinlẹ Ogun ṣi ofiisi tuntun l'Abẹokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 14 June 2024

Ẹgbẹ oṣelu ADC ipinlẹ Ogun ṣi ofiisi tuntun l'Abẹokuta

L'Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, ipinlẹ Ogun, ṣi ọfiisi tuntun nibi tawọn oloye ẹgbẹ ọhun lapapọ ti peju pesẹ, eyi to waye lagbegbe Itoko, niluu Abẹokuta.

 

Lara awọn to wa nibẹ ni alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Ralph Nwosu,alaga ẹgbẹ wọn nilẹ Yoruba, Ọgbẹni Rasak Eyiowuawi, alaga ẹgbẹ ADC nipinlẹ Ogun, Itunu Abioro, bẹẹ naa ni alaga fẹgbẹ awọn apapọ oloṣelu nipinlẹ naa, IPAC, Ọgbẹni Abayọmi Sanyaolu atawọn mii-ii.

 

Ninu ọrọ Nwosu lo ti bu ẹnu atẹ lu aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori bi ko ṣe fi apẹẹrẹ aṣaaju rere lelẹ lori ti ayẹyẹ ayajọ ọdun dẹmokiresi to maa n waye lọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdọọdun.

 

O sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ pe pẹlu bi Tinubu ṣe jẹ ọkan lara agba ẹgbẹ NADECO, ko ṣe bii aṣoju rere fun ijọba dẹmokiresi ti Abiọla ja fun.  Nitori bi ilu ṣe le koko tawọn araalu koju awọn ipenija lọtun ati ni osi paapaa julọ nipa ọrọ aje ati eto aabo.

 

Alaga ẹgbẹ naa lapapọ tun fikun ọrọ ẹ pe ẹgbẹ oṣelu ADC, ti ṣetan lati gba akoso Aso Rock iyẹn lọdun 2027, tawọn yoo si ri pe awọn tẹle igbesẹ MKO Abiọla ninu iṣejọba wọn.

 

Bẹẹ lo sọ pe ọkan lara aṣiṣe ti Tinubu ṣe ni bo ṣe yọ owo sobsidi kuro, eyi lo si sọ pe o n da wahala silẹ tawọn araalu fi n koju ipenija lati bi ọdun kan to ti gbajọba.O ni iru idaamu bayii lo ko le tete yanju laarin ọdun mẹfa si akoko yii.

 

O ni iyalẹnu lo jẹ pe pẹlu bawọn araalu ṣe n daamu lojoojumọ Tinubu tun le fọwọ si ile olowo nla ti wọn kọ fun igbakeji ẹ, Alaaji Shettima.O waa rọ awọn araalu lati ṣe suuru nitori igba diẹ lo ku tijọba APC yoo fi kogba wọle ti ADC, yoo si gbajọba.

 


No comments:

Post a Comment

Pages