Ojiṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Isreal Ogundipẹ, tijọ Genesis Global, ti rọ awọn alagbara ti Ọlọrun gbe agbara lee lọwọ lati maa fẹṣọ ṣe o, nitori ko yẹ ki a maa lo ọwọ agbara lati maa fi gba ara wa, ẹṣẹ ati ijiya nla lo pe e.
Ọkunrin naa sọrọ yii nitori awuyewuye kan to n lọ nigboro Eko, nibi ti wọn ti fẹsun kan ọmọ aarẹ orileede yii Ṣeyi Tinubu atawọn eeyan ẹ kan lori bi wọn ṣe fẹẹ lo ọwọ agbara wọn lati gba ilẹ ti wọn ni makẹta, to n gbe awọn olorin jade, iyen Abel Abu ra si agbegbe Ologolo,Eti-Ọsa, Lekki, Ajah, nipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọkunrin naa lo kọkọ ra ilẹ naa amọ ni bayii ti wọn ti ko idaamu ba a.
Wolii Ogundipẹ ṣalaye siwaju pe ko yẹ ki iru nnkan bẹẹ maa waye laarin awọn to ba ni ibẹru Ọlọrun.
O sọ pe Abu Abei ti wọn lo maa n ṣagbatẹru awọn ọdọ ti jiya pupọ lori ilẹ naa, ko wa yẹ ko jẹ pe akoko yii ni wọn yoo maa lo orukọ ọmọ aarẹ orileede yii iyẹn Ṣeyi Tinubu lati gba ilẹ ọhun.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa tun sọ pe oun mọ Ṣeyi Tinubu gẹgẹ bi ẹni ti ki i gba ẹgbin mọra, idi niyii ko fi tete jade sọrọ naa, ko da ilẹ ọhun pada fun Abu Abel, ti wọn lo ti kọkọ ra ilẹ yii.
O ni kawọn eeyan naa fi ibẹru Ọlọrun si ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe, nitori oun lo ni gbogbo nnkan nikawọ.
Bẹẹ lo tun sọ pe ko yẹ kawọn ọdọ tun maa jẹ ara wọn lẹsẹ niwọngba to jẹ pe idagbasoke ilu naa ni gbogbo wọn n wa lorileede yii.
No comments:
Post a Comment