Ẹṣọ aṣọbode ipinlẹ Ogun ṣawari apo gaari ti wọn ko ọta ibọn pamọ si - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 15 March 2024

Ẹṣọ aṣọbode ipinlẹ Ogun ṣawari apo gaari ti wọn ko ọta ibọn pamọ si



Ọga agba fun ẹṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Ahmadu Shuaibu, ti sọ pe awọn ti ṣawari ibi kan tawọn afurasi kan ko ọta ibọn ẹẹdẹgbẹrun le ogoji si, eyi to ni wọn n pinnu lati ko wọlu.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ṣafihan awọn nnkan naa fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaide. Gẹgẹ bo ṣe wi, ninu apo gaari lo sọ pe wọn ko awọn ọtan ibọn ọhun si, ti wọn si n gbiyanju ọna ti wọn le gba gbe wọ orileede yii.

 

O sọ pe lọjọ Tọsidee, tii ṣe ọjọ kẹrinla, oṣu yii, lawọn ri awọn ọta ibọn naa lẹyin bii ọsẹ meji tawọn fi n sọ wọn lati orileede Benin, ko to di pe o ni wọn rapala wọlu. O ni bawọn kan ṣe tawọn lolobo lawọn ti mu eto aabo agbegbe lọkunkundun tawọn ṣo wọn lọ, ṣọ wọn bọ.

 

Shuiabu tun fi kun ọrọ ẹ pe awọn alaabo naa ṣiṣẹ takuntakun ti wọn si ri ẹru naa nibi ti wọn gbe pamọ si amọ ti awọn fayawọ to ko o wọlu si sa lọ mọ wọn lọwọ, nitori ki wọn ma ba a mu wọn.

 

 

Bakan naa lo tun sọ pe awọn ri apo ọgọfa le mẹta ti wọn ko igbo sinu ẹ, awọn aṣọ tokunbọ, paali ẹẹdẹgbẹrun le mẹwaa ti wọn ko tọki sinu ẹ eyi to sọ pe awọn gba lawọn ẹnu ọna to paala kaakiri ipinlẹ Ogun. O ni gbogbo owo nnkan ti wọn ri gba jẹ miliọnu lọna ẹgbẹta Naira.

 

O fikun ọrọ ẹ pe idunnu awọn lo jẹ pe pẹlu gbogbo iṣẹ tawọn ti n ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii ko sẹni to farapa tabi nijamba, o ni eyi jẹ lara aṣeyọri fawọn, nitori pe awọn jẹ ki wọn mọ pe awọn mu ẹmi awọn eeyan ni Pataki, idi niyii tawọn fi n daboobo wọn.

 

O sọ pe, ‘’ Mo fẹẹ  jẹ ko ye gbogbo awọn araalu pe awọn oṣiṣẹ wa ti wọn n gbe nnkan ija oloro da ni fi n daboobo ara wọn ni nibi to ba yẹ, nitori nnkan ki nnkan to ba fẹẹ  dunkoko mọ ẹmi wọn,ko nii farare lọ. Bẹẹ ni mo tun fi akoko yii sọ fawọn fayawọ pe igba perete ni akoko wọn ku, wọn ko nii lọ laijiya ẹsẹ wọn’’.

 

Ọga aṣobode nipinlẹ Ogun, ti wa rọ awọn ọmọ orileede lati tẹsiwaju ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn aṣọbode lati le jọ gbogun ti awọn fayawọ ti wọn n ko awọn nnkan ija oloro wọlu.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages