Ija to ṣẹlẹ ni Agewe mi o mọ ohunkohun nipa ẹ--Oloye Rafiu Ẹlẹlẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 1 March 2024

Ija to ṣẹlẹ ni Agewe mi o mọ ohunkohun nipa ẹ--Oloye Rafiu Ẹlẹlẹ



Ọjọ Tuside iyẹn ọjọ iṣẹgun ọsẹ to kọja lọ yii lawọn ọdọ agbegbe abule Agewe nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode nipinlẹ Ogun kọju ija si ara wọn ti aṣiri si ti pada tu pe awọn ọmọ egbe okunkun Aiye ati ẹiyẹ ni wọn n ba ara wọn ja ṣugbọn tawọn kan ti n sọ pe oloye Rafiu Oseni Ẹlẹlẹ mọ nipa iṣẹlẹ naa ṣugbọn ti aṣiri ti pada tu sita pe awọn ọbayejẹ kan ni wọn wa nidi ọrọ naa latari ayẹyẹ ọjọ ibi baba alaanu mẹkunnu naa ti yoo waye lọjọ keje oṣu kẹta ọdun yii
Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lo ti sọ pe oloye kan laarin ilu naa to tun jẹ ajagungbalẹ lo n lo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii lati maa dẹruba awọn ara agbegbe naa ti eyi si dija nla ti ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ ọgbẹni naa to n jẹ Shaolin si ti sọnu titi di asiko yii
Oloye Ẹlẹlẹ sọ pe awọn ọta ti ko fẹ ki ayẹyẹ ọjọ ibi oun nibi tawọn opo,arugbo,ọmọ alailobi ti maa n jẹ anfaani,onjẹ,owo,ẹbun fọọmu jambu ọfẹ waye lo ṣe jẹ ki wọn fẹ fi wahala to ṣẹlẹ naa kọ oun lọrun
Oloye Ẹlẹlẹ to tun jẹ Alaaji to fẹran awọn ọdọ ti wa sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa ati pe ibi ti Shaolin iyẹn Rasaki wa titi di asiko yii ni ẹnikẹni ko le sọ,bẹẹ lo sọ pe oun n fifẹ pe awọn opo atarugbo sibi ayẹyẹ ọjọ ibi oun ọdun nitori bi oun ṣe ma n ṣe lọdọọdun ni yii

No comments:

Post a Comment

Pages