Ileewe olukọni FCE Oṣiẹlẹ bẹrẹ ayẹyẹ ikẹkọọjade ẹlẹkẹẹdọgbọn - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 3 March 2024

Ileewe olukọni FCE Oṣiẹlẹ bẹrẹ ayẹyẹ ikẹkọọjade ẹlẹkẹẹdọgbọn



 

Gbogbo eto lo ti to fun ayẹyẹ ikẹkọọjade ẹlẹkẹẹdọgbọn awọn akẹkọọ wọn ati ọdun kejidinlaadọta ti wọn da ileewe naa silẹ.Eyi ti wọn ti bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin in ni, oṣu yii.

 

Gẹgẹ bi atẹjade latọdọ Alagba Gabriel Adebayọ,to jẹ akọwe agba nileewe ọhun fi sita, lo ti sọ pe oriṣi awọn eto lo ti wa nilẹ fun ayẹyẹ ọlọsẹ kan naa, ti yoo pari lọjọbọ, Tọsidee, ọjọ Keje, oṣu yii.

 

Ọjọ Jimọ ni wọn lọọ kirun Jumat lọgba ileewe naa nigba ti isin idupẹ waye lonii, ni ṣọọṣi ‘Chapel of Peace’, FCE Abẹokuta. Ni ọla ọjọ Aje ni wọn yoo rin fun ere idaraya. Nigba ti ipade oniroyin yoo si waye lọsan-an, ọjọ naa.

 

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn la silẹ fun ayẹwo ara, nigba ti ayẹyẹ orin ati ere fun ikẹkọọjade iyẹn yoo waye laago mọkanla aarọ ni gbọgan tiata wọn, ere idije bọọlu ọlọrẹsọrẹ ni wọn yoo fi pari ẹ lọjọ naa.

 

Ọjọọru, Wẹsidee, ni idanilẹkọọ yoo waye ni gbọngan Dokita Kunle Filani. Aṣalẹ ọjọ naa ni fifi ami ẹyẹ dawọn eeyan lọla ati ere ibilẹ. Nigba ti ayẹyẹ ikẹkọọjade yoo waye l’Ọjọbọ, Tọsidee ni gbọngan Adukẹ, lọgba ileewe naa.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages