Bo tilẹ jẹ pe titi digba taa fi n kọ iroyin yii, a ko le so pato nnkan to ṣokunfa iku ẹ, ṣugbọn ohun taa gbọ ni pe ọsibitu Ladoke Akintọla to wa ni Ogbomọṣọ lo dakẹ si lọsan yii.
Ọpọ awọn oṣere tiata lọrọ naa n jọ bi ala loju wọn, to fi mọ awọn oloolufẹ ẹ, ibeere ti wọn si n beere lọwọ ara wọn ni pe ṣe loootọ ni.
Bẹẹ lawọn oṣere mii-ii si ti n kẹdun iku Sisi Quadri yii lori ẹrọ ayelujara. Ni nnkan bi ọdun meloo kan sẹyin ni irawọ oṣere naa bẹrẹ si nii jade nigba to kopa ninu ere Ajilẹyẹ.
Nitori bo ṣe maa n ṣe bi obinrin ni wọn ṣe n pe ni Sisi Quadri ati pe lọpọ igba ni wọn tun maa fun ni ipa ti yoo ti ṣe ẹẹkẹ eebu, eyi to jẹ ki irawọ ẹ tubọ tan.
No comments:
Post a Comment