Ṣe ni inu awọn ọmọ alainiya to wa ni Ijamido, nilu Ọta dun, nigba ti Oloye Rafiu Oṣeni Ọkanlawọn tọpọ awọn eeyan mọ si Ẹlẹlẹ ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ pẹlu wọn. Bẹẹ ni gbogbo n fi ọkan ṣadura fun ẹlẹyinju aanu naa fun bo ṣe ranti wọn.
Oloye Ọkan lawọn to nileeṣẹ Ẹlẹlẹ Real Estate, ni o maa n fi idunnu ẹ han ni gbogbo ọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun, fun ti ayẹyẹ ọjọọbi ẹ, to si tun maa n lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun. Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun lo ti sọ pe pataki lawọn ni awọn ọmọ alainiya tabi alabọ ara lawujọ to si yẹ ki wọn maa mu inu wọn. Laada kan lo pe lati ọrun wa.
Bakan lo tun sọ pe ọjọ keje,oṣu kẹta , jẹ aye ọpẹ foun, toun ko si le fi ṣere ati pe gbogbo nnkan to ba waa nikawọ oun lo gbọdọ maa fi ran awọn eeyan lọwọ . Bẹẹ lo sọ pe ileeṣẹ Ẹlẹlẹ Real Estate yatọ ninu awọn to n ta ilẹ, nitori pe ibẹru Ọlọrun lawọn fi n ṣiṣẹ.
O waa gba gbogbo awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ lamọran lati maa ranti awọn to ba ku diẹ kaato fun lawuja. Apagunpọtẹ fun ilu Igbein wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn oloolufẹ ẹ fun atilẹyin nla ti wọn ṣe fun oun.
No comments:
Post a Comment