Oga ileewe olukoni ijoba apapo to wa ni Osiele, niluu Abeokuta iyen FCE, Dokita Rafiu Adekola Soyele, ti ro ijoba apapo lati je kawon ileewe olukoni maa kekoo fun digirii pelu ti olukoni ti won ko won, ko le baa tun mu iwuri wa.
Oga ileewe naa soro yii nibi ipade oniroyin to waye fun ti ikekoojade keedogbon ati kejidinlaadota ti won da ileewe naa sile, eyi to waye ninu ogba ileewe yii.
Soyele so pe bi won ko ba tete gbe igbese o see se ki won pa ileewe olukoni re patapata ko si di oun itan, idi niyi ti won fi ro ijoba apapo lati gbe ki won maa kekoo digirii lawon ileewe olukoni naa.
O tun fikun oro e pe iye awon oluko tileewe olukoni ti ko o jade koja nnkan afenuso, ti ko si safiwe e gan lawon ileewe yunifasiti.
O salaye pe enikeni to ba jade niwe eri olukoni pelu ti digirii yoo tun ni afikun imo lati di oludasile tabi oga ileewe.
Bakan naa lo tun so pe gbogbo erongba won lati je ki ileewe naa tubo maa tesiwaju lawon n tele bee lawon ko kaare, o wa ro ijoba apapo lati tubo maa satileyin fun won.
Pelu bi ayeye ikekoojade keedogbon ati kejidinlaadota idasile naa se n lo lowo, oga agba naa so pe idanilekoo yoo waye nibi ti Ojogbon Tunji Olaopa yoo ti dawon kekoo.
Pabanbari e ni ayeye ikekoojade ti yoo waye lojo Tosidee, ose yii ninu ogba ileewe naa.
No comments:
Post a Comment