Iroyin kọja afẹnusọ lọjọ Tọsidee, ọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun yii, niluu Ilate-Etido, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, nigba ti Oloye Shamseeden Akintunde Ajibawo, ṣayẹyẹ ọdun kin in ni to di Baalẹ.
Ṣe awọn araalu ọhun duro ti Baalẹ naa fun ayẹyẹ yii debi pe gbogbo awọn ọmọ ilu yii to wa kaakiri ipinlẹ ni wọn wa yẹ ọba naa ti wọn ṣapejuwe pe latigba to ti gun ori itẹ lo ti mu idagbasoke ba wọn, ti ko si fọrọ wọn ṣere pẹlu
Bi awọn ẹlẹsin musulumi ṣe wa ṣadura bẹẹ ni awọn olori ijọ Methodist naa wayẹ Baalẹ naa si, ti gbogbo wọn si n gbadura pe ki Ọlọrun tubọ fun ni okun ati agbara ti yoo fi tubọ mu itẹsiwaju ilu, ti nnkan yoo si fi maa dun yungba fun tonile ati alejo to n gbe ilu yii.
Ninu ọrọ Ọba Onirọ, tilu Irọ,nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, Ọba Nojeemdeen Alani Eyiowuawi Aromaye, lo ti fi iduunu ẹ han si Baalẹ Akintunde Ajibawo, fawọn aṣeyọri to ti ṣe laarin ọdun kan to gori oye, o sọ pe iwuri nla lo jẹ foun ati pe oun ko kabamọ pe oun fi i joye naa.
Bẹẹ lo tun ṣeleri atilẹyin fun Baalẹ naa pe gbọingbọin loun wa lẹyin ẹ. O tun sọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ latigba ẹtọ awọn eeyan Ilate-Etido pada fun wọn, nitori gbogbo bi wọn ṣe ni onitọhun fara ni awọn araalu ọhun lawọn ti gbọ, tawọn yoo si rii pe wọn ko jẹ awọn eeyan naa mọ aye.
Ọba Onirọ tun fikun ọrọ ẹ pe gbogbo awọn ilu to wa lọba Onirọ loun yoo rii pe wọn wa nirẹpọ, ki alafia le tubọ maa jọba laarin wọn. O waa rọ gbogbo awọn araalu Ilate-Etido, lati tubọ maa ṣatilẹyin fun Baalẹ wọn, nitori gbogbo wọn lo mọ pe igi kan ko le da igbo gbe.
Gẹgẹ bi iwadii oniroyin, a gbọ pe latigba ti Baalẹ tuntun ọhun ti jẹ lo ti n gbe igbesẹ aye irọrun fawọn eeyan ẹ, lara ẹ ni tileewe ti wọn ti pati lati nnkan bi ọdun meloo sẹyin, to ji dide pada, nibẹ lawọn ọmọleewe wọn lọ bayii.
Bẹẹ lo si ti n rii pe ajọṣepọ n wa laarin ijọba ipinlẹ Ogun ati ilu ẹ yii lati le rii pe wọn dẹrin pẹẹkẹ awọn eeyan yii. Amọ sa o, Baalẹ ọhun ti sọ pe diẹ lawọn araalu naa si ri ninu nnkan to wa niwaju oun lati ṣe ati pe nnkan to wa lẹmi oun ni pe ki ilẹ naa di ibi ti wọn yoo ti maa wa da ileeṣẹ nla silẹ, ki awọn ọna ti ko dara bẹrẹ si ni atunṣe.
No comments:
Post a Comment