Ileeṣẹ aṣọbode nipinlẹ Ogun, ti rọ awọn ọdọ ti wọn wa lawọn agbegbe ẹnubode to paala lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn lati le jẹ ki fayawọ di oun igbagbe, nitori akoba nla lo mu ba orileede Naijiria.
Ọga agba fun ileeṣẹ naa, Ahmadu Bello Shuaib, lọ sọrọ naa nibi apero kan to waye, eyi ti ileeṣẹ aṣobode pẹlu awọn ọdọ ijọba ibilẹ Ipokia, jọ ṣe papọ, ẹlẹẹkarun ẹ, to waye ni ootẹli, Mercyland, Idi-Iroko, nipinlẹ Ogun.
Igbakeji ọga agba naa, Charles Ogunesan, to ṣoju Shuaib, nibi eto ọhun ṣalaye pe laaarin ọdun kan sẹyin, ọpọ iriri lawọn ti ri lakooko ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ pẹlu awọn fayawọ.
Lara ẹ ni bi wọn ṣe fẹẹ maa di wọn lọwọ lẹnu iṣẹ, gbe ija kọ wọn loju, bakan naa lo ni ṣe lawọn fayawọ yii atawọn olubanikẹdun wọn maa n gbegi saarin oju titi, ti wọn yoo dana si, nitori kawọn oṣiṣn wọn ma ba le kọja.
Bẹẹ ni Shuaib tun sọ pe ki i ṣe ọrọ tẹnu awọn oṣiṣẹ wọn ti wọn ti ṣe nijamba ko ṣe e fẹnu sọ, o waa ni akoko ti to bayii lati fopin si iru nnkan bayii to si rọ awọn ọdọ ti wọn wa lagbegbe naa, ki wọn yẹra fawọn nnkan to le ba wọn lorukọ jẹ.
O ni ọpọ awọn oṣiṣẹ wọn ni wọn ti pa danu, nigba tawọn kan ti di alaabọ ara, bẹẹ lo ni iri nnkan bẹẹ waye lsawọn agbegbe tawọn naa padanu eeyan wọn nipasẹ awọn onifayawọ yii.
Gẹgẹ bi akori wọn tọdun yii, ti wọn pe ni ‘’Fayawọ, gbigbe epo pẹtiroolu, aleebu to n mu ba agbegbe ati eto abo lapapọ’’ nibẹ ni Ogunẹsan to ṣoju ọga agba wọn tun ti sọ pe asiko ti wa to bayii ki gbogbo wọn jọ ṣiṣẹ pọ pẹlu imọ kan lati gbogun tawọn onifayawọ yii, ki idagbasoke le de ba ọrọ aje ati eto aabo wa.
Bakan naa ni ọga awọn kọsitọọmu tun sọ pe laarin oṣu kin in ni si akoko yii owo tawọn fayawọ ọhun ti padanu sọdọ awọn aṣọbode fẹẹ to biliọnu meji naira.(N1, 514, 478, 916.00).
O ni ka ni wọn na iru owo bẹẹ sinu okoowo ni yoo tun jẹ ke eto ọrọ aje orileede yii tun lọọ si oke si.
No comments:
Post a Comment