Lọsẹ to kọja ni ọga agba pata lorileede yii, Bashir Adeniyi, tu aṣiiri ọna tawọn onifayawọ gba gbe igbo wọ orileede yii, ṣugbọn tawọn ti kapa wọn bayii. Gẹgẹ bo ṣe wi oriṣi ọgbọn alukọrọmi ni wọn n gba lati ri pe wọn n ko egboogi oloro yii.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ṣafihan awọn ẹru ofin ti wọn gba lọwọ awọn onifayawọ, eyi to waye ni Idi-Iroko, nipinlẹ Ogun, lọsẹ to kọja, o sọ pe ọtalelẹẹdẹgbẹta igbo, eyi ti kilo rẹ fẹẹ to ẹgbẹrun kan ati ọgọrin ni wọn ga lakooko ti wọn gbindanwo lati ko o wọ orileede yii.
O salaye siwaju pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti wọn ti n ko awọn nnkan bẹẹ wọlu ko to di pe ọwọ palaba wọn ṣẹgi. Bakan naa lo tun fikun ọrọ ẹ pe awọn tunri taya ati apo irẹsi gba lọwọ wọn pẹlu.
Ọga agba agba pata ọhun ti ọga wọn nipinlẹ Ogun wa lẹgbẹ ẹ tun sọ pe laarin ọsẹ meji to kọja ni ajọ aṣọbode tun gba apo baagi irẹsi ẹgbẹrun mẹta le ni aadọjọ ti kilo rẹ jẹ aadọta pẹlu mọto mejilelọgbọn ti wọn fi ko wọn wọlu.
Adeniyi tun wa sọ pe ni abẹ isakoso ajọ aṣọbode lorileede yii, gbogbo ọna lawọn n n sa lati ri pe wọn dẹkun ijamba mọto, idi niyii tawọn fi n gbogun tawọn to n ko aloku taya wọlu.
O sọ pe aburu nla ni kiko awọn aloku taya ọhun ti wọn pe ni Tokunbọ n ṣe fawọn to ni mọto lorileede yii ati pe ati pe akoko ti to lati fopin si.Bẹẹ lo tun fi aidunnu ẹ han lori bawọn ọdọ ṣe n fojoojumọ gbilẹ si ninu mimu egboogi oloro bii igbo.
O waa sọ pe awọn oṣiṣẹ wọn ko ni sinmi lati gbogun tawọn to n gbe igbo naa jade. O ni apapọ owo nnkan ti wọn ri gba lọwọ awọn fayawọ jẹ miliọnu lọna ojilenigba naira lawọn agbegbe bii Papa-Ajegunlẹ-Ilaro, Imasayi-Joga, Ijẹbu-Ode ,Odogbolu atawọn ibo mii-ii
No comments:
Post a Comment