Oguntoyinbo ro awọn ọdọ lagbara eronja ti wọn fi tun foonu ṣe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 28 September 2023

Oguntoyinbo ro awọn ọdọ lagbara eronja ti wọn fi tun foonu ṣeAgba ọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP),Kọmureedi Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, ti rọ awọn ọdọ lati rii pe wọn mu iṣẹ wọn lọkunkundun ju, pe ki won maa rin regberegbe kaakiri.

O ni eyi ṣe pataki nitori bi ọrọ aje ṣe n fojoojumọ lọọ sẹyin lorileede yii, tijọba ko si ṣetan lati pese iṣẹ fun miliọnu awọn ọdọ ti wọn ti kẹkọọ jade ṣugbọn ti wọn ko niṣẹ.

Ajadi to ti figba kan jẹ oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun nipinlẹ Ogun, sọrọ naa lakooko ti wọn pari eto ọlọsẹ meji kan, nibi ti wọn ti da wọn lẹkọọ nipa bi wọn ṣe n tun foonu ṣe, nibi ti aadọta ọdọ ti kopa, to waye niluu Ibafo, nipinlẹ Ogun.

O sọ pe idanilẹkọọ to waye ọhun jẹ lara ọna toun gba ṣatilẹyin fawọn ọdọ lori ipenija ti wọn koju lori ọrọ aje lorileede yii. Nibẹ lo ti fawọn mẹẹdogun ninu wọn ni awọn eroja ti wọn fi n tun foonu ṣe.

Kọmureedi Olowu Ọlayẹmi, to jẹ alukoro ẹgbẹ naa lo ṣoju Ajadi nibi ayẹyẹ naa, tun waa gba awọn ọdọ lamọran kọju mọ nnkan ti wọn n ṣe nitori ọjọ iwaju wọn.

O ni ki wọn  ma ṣe ro ibẹrẹ, nitori o sọ pe o lewu ṣugbọn ni pari ohun gbogbo ayọ ni yoo gbẹyin fun wọn. O waa gba ironilagbara awọn ọdọ naa gẹg bi ipe lati ọdọ Ọlọrun, lati ran awọn eeyan lọwọ.

Bẹẹ lo rọ gbogbo awọn to kopa nibi idanilẹkọọ naa atawọn to jẹ anfaani eroja titin foonu ṣe ọhun lati jẹ aṣoju rere, eyi ti yoo wu oun lori lati tun le ṣe ju bẹẹ lọ.

Ninu ọrọ Abdul Akeem Yusuf, to nileeṣẹ ‘’Hasbunallah Communication Ventures’’, to jẹ alagbatẹru eto ọhun fi idunnu ẹ lori bi wọn ṣe ṣe aṣeyọri ati pe o tun fimọ kun imọ awọn to kẹkọọ naa.

Bakan naa ni Pasitọ Godwill Mathew, to jẹ oludari ijọ Ridiimu, Pinnacle of Glory Parish,  o gboriyin fun Ajadi fun bo ṣe ran awọn eeyan lọwọ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages