Ọpọ awọn ọba alade nilẹ Yoruba ni wọn ko pọn ara wọn le- Aarẹ OPC New Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 27 September 2023

Ọpọ awọn ọba alade nilẹ Yoruba ni wọn ko pọn ara wọn le- Aarẹ OPC New Era



Aarẹ fẹgbẹ Oodua Peoples Congress, New-Era, Oloye Rasak Arogundare Balogun, tọpọ mọ si Saddam ti sọ pe bi Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ṣe kan awọn ọba labuku, ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin, dun mọ oun ninu gan-an ni, nitori awọn ọba yii ni wọn ti n fara wọn wọlẹ tipẹ.

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ ni ọfiisi ẹ, o sọ pe ọpọ ọba oloṣelu lo pọ nita bayii, ti ki i ṣe ẹni tawọn araalu tabi ifa yan fun wọn, idi niyii to fi jẹ pe o digba ti wọn ba pada si bi wọn ṣe n yan ọba laye atijọ, ki ayipada rere tun le ba wọn.

Arogundade sọ pe,’’ Nitootọ ọtọ  ni oju ti gbogbo wa fi n wo o, oju tawọn kan fi wo, wọn nigbagbọ ninu ilana, bo ṣe yẹ ko ri niyẹn, o yẹ kawọn ọba le dide lati pọn Gomina le, oju tawọn mi-in tun fi wo ni pe be abuku ni  baba fi kan awọn ọba yẹn, amọ bi emi gẹgẹ bi ẹnikan, oju temi fi wo yatọ si gbogbo ti wọn, inu temi dun si nnkan to ṣẹlẹ’’.

‘’Nitori fun kin ni? Gbogbo ẹda ti ko ba ti mọ nnkan to tọ, ti ko si yẹn ni nnkan tootọ, ti abuku ba kan an, ko yẹ ka a kanu ẹ. Nnkan to kan kọ wa lominu ni ipo ti wọn wa, ti wọn tabuku si, ibeere temi ni pe ṣe gbogbo awọn ti wọn fi jọba, lo ni ẹtọ si ọba bi?

‘’Ọpọ wọn ko lẹtọọ si, ọba oloṣelu ni gbogbo wọn, oloṣelu lo fi wọn jọba, awọn kọ  niluu fọwọ si tabi yan an, ki i ṣe bo ṣe tọ ni ọpọ wọn fi dori oye, bo ṣe gba ni.

‘’Fun apẹẹrẹ, ẹ woo, ilu Ogbomọṣọ, ọba ti wọn fi jẹ nibẹ, awọn idile ẹ gbe e lọ sile-ẹjọ, wọn ko si ninu ẹni tawọn fọwọ si tabi yan , ṣugbọn nigba ti jọba sọ pe nnkan tawọn n fẹ niyẹn n kọ’’?

O ni boya ẹnikan lo lọwọ agbara ẹ, to sọ fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, pe  ẹni tawọn fẹẹ ko  jẹ ọba niyẹn, boya ọba ko si tọ ọ si, awọn ko le sọ. O ni wọn ko da ifa, wọn ko wo akẹsẹjaye ẹ.

O waa fikun ọrọ ẹ pe biyẹn ba wa debẹ laarin oṣu mẹfa si ọdun kan, to n ṣe wọnranwọnran, wọn yoo wa sọ pe o n ba aṣa jẹ laimọ pe awọn alaalẹ lo n binu.

O ni, ‘’Ṣe awọn to mọ nipa aṣa wa tabi awọn to tọ ni a n fi sibẹ? Ọnakọna ni irunmọlẹ fi n fiya jẹ eeyan, awọn ọba ta a n sọrọ yii, bi ẹ ba ni ki wọn ṣadura, omii-ii a sọ pe lorukọ Jesu,awọn mii-ii ni afin wọn, ojoojumọ ni wọn ṣe iṣọji nibẹ’’.

‘’Awọn nnkan ta a fi sọ, to jẹ oriṣa wọn ti gbagbe ẹ. Bi ọba ba wọ ipebi to ba a jade, iwọ gan-an a mọ pe wọn ti di alagbara.Bi  ẹni ba wa kan wọn nikoo, ko yẹ ki a kaanu wọn.’’ Awọn ọba ṣẹṣẹ bẹrẹ nii kan abuku ni, eyi to maa kan wọn yoo si ju bẹẹ lọ. Iru ọba Ogbomọṣọ ti wọn yan yii, ti wọn ni ko si ninu awọn to lẹtọọ si ọba, ti Ṣeyi Makinde waa pọn- ọn dandan le wọn lori, ọba oloṣelu la maa pe iru wọn.

‘’Ti Gomina ba waa paṣẹ fun un, ko to bẹẹ lati maa mu ṣẹ. Aṣa wa ko ni ki a ma ṣe ẹsin, o yatọ si ara wọn, awọn ọba kan waa pa aṣa ti, ẹdun ọkan lo si jẹ pe awọn oyinbo pọn ọn le ju wa lọ, ti wọn si  gbe larugẹ’’.

‘’Ẹyin ti ẹ waa jẹ alaṣẹ keji oriṣa,  alaṣẹ oriṣa kẹ, ẹ o ni aṣẹ kankan mọ, awọn to ba n pe yin bẹẹ, wọn tan yin jẹ ni.

‘’ Nibi ti ọrọọ naa buru de alaga ijọba ibilẹ lẹnu ju wọn lọ, ọba to ba ti rin regberegbe ti wọn ba kabuku ẹ, a o gbọdọ kaanu wọn, nnkan ti wọn tọ ni wọn gba, awọn irunmọlẹ lo mọ-ọn mọ fi wọn ṣe ẹsin. Ki awọn naa pada si orirun wọn, ti wọn ba le ṣe bẹẹ, wọn yoo mọ nnkan to tọ ati eyi ti ko tọ.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages