Ọmọ ale Yoruba nikan lo maa ni bi Aarẹ Tinubu ṣe n pin ipo pataki fawọn ọmọ Yoruba ko daa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 25 September 2023

Ọmọ ale Yoruba nikan lo maa ni bi Aarẹ Tinubu ṣe n pin ipo pataki fawọn ọmọ Yoruba ko daa 

 Àyà nini to oogun lọtọ, ka ni igboya ka si le ṣe bii ọmọ akin ki i tan lọrọ ẹni to ba ya akin.  Eyi lo fa a ti Aarẹ ẹgbẹ Odua People’s Congress Reformed, (OPC-R) lagbaaye, Kọmureedi Dare Adésopé, ṣe f’ọwọ rẹ gbaya, to ni eegun loun n fọwọ sọ o, ki i ṣe ẹran rara. O ni walahi, boun ba wa nibi ti aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti paṣẹ fawọn ọba alaye nipinlẹ Ọyọ pe ki wọn dide ni, awọn Oriade naa ko ni i dide fun un, kinni kan ko si ni i ṣẹlẹ.

 

Nibi ifọrọwerọ ti ẹgbẹ akọroyin ledee Yoruba, League Of Yoruba Media Practitioners (LYMP),  ṣe lori ayelujara pẹlu Aarẹ Adesope l’Ọjọruu lo ti sọrọ yii pẹlu alaye lorii idasilẹ ẹgbẹ OPC Reformed, Oloogbe Fredrick Faseun, Iba Gani Adams ati bẹẹ bẹẹ lọ:

 

‘’Orukọ mi ni Kọmureedi Dare Adesope, mo jẹ Aarẹ ẹgbẹ Oodua Peoples’ Congress Reformed. Emi ni Akọwe agba fun Ọmọwe Fredrick Fasehun nigba kan.

 

Nnkan to bi OPC Reformed, ẹ ri i pe OPC Reformed la n pe e, labẹẹ Ọmọwe Fredrick Faseun lati kuro nigba yẹn, nnkan to dẹ bi i ni pe o di pe ẹgbẹ yẹn fẹẹ ṣe lodi si nnkan ta  a n polongo. A fẹẹ ṣe lodi si nnkan ta a duro fun pe ninu gbogbo nnkan ki nnkan ta a ba n ṣe, Yoruba lo maa jẹ akọkọ ta a maa ja fun, ta a maa duro ti .

 

Nigba idibo Buhari ati Ọṣinbajo, ko too digba yẹn, gbogbo wa naa la ri i pe Yoruba wa lẹyin gan-an ninu ọrọ Naijiria, nnkan ta a dẹ n ja fun naa ni niyẹn, ẹẹmẹwaa la maa n ba ẹyin oniroyin sọrọ, pe wọn n ko iyan wa kere niluu Naijiria.

 

Igba to wa digba ibo yẹn, ta a wa ri i pe bo tiẹ ṣe le wu ko ri, ipo igbakeji ni Naijiria ki i ṣe ipo to kere naa, ọmọ Yoruba leleyii o. Ṣugbọn Baba to jẹ aṣiwaju wa nigba yẹn, awọn o lọ sibi yẹn, nitori pe Jonathan ṣe awọn ileri kọọkan fun wa. Gẹgẹ bẹ ẹ ṣe mọ pe ninu OPC na lotitọ ati lododo, ororo ara wa la fi n yan ara wa, a maa n funra wa gbẹ ni ka too ri nnkan kan ṣe ninu ẹgbẹ yẹn.

 

Jonathan wa ṣeleri pe ta a ba ṣiṣẹ foun toun ba debẹ, oun maa gbe iṣẹ ida-aabo-bo ọpa epo fun wa atawọn oriṣiiriṣii nnkan bẹẹ yẹn, o dẹ mu awọn ileri yẹn ṣẹ.

 

Ṣugbọn ṣe ẹ mọ, emi atawọn kan la wo o pe nibo la fẹẹ foju si i, awa ta a la n ja fun Yoruba lododo, ka tun wa tori ohun ta a fẹẹ jẹ, ka wa ba ohun ti a fẹẹ jẹ́ jẹ́. A wa la duro pe a o ni i ṣe iru eleyii, bo ṣe le wu ko ri, ẹgbẹ to gbe ọmọ Yoruba jade gẹgẹ bii Igbakeji lawa maa ṣiṣẹ fun.

 

Kinni yẹn da gbọnmi-si i-omi- o to o silẹ ninu ẹgbẹ to jẹ pe wọn ti wa mọle, wọn lo ọwọ agbara fun wa. Ṣugbọn nitori pe a ni afojusun, a dẹ n wo ba a  ṣe jẹ, ọmọluabi la pera wa, a dẹ n ranti ile, fun idi eyi, a duro lori ẹsẹ wa, a ko jẹ ki gbogbo awọn nnkan yẹn mi wa.

 

    Nigbẹyin ṣaa, nigba to di oṣu kẹwaa ọdun 2016, a fi ẹgbẹ tiwa lelẹ ti i ṣe OPC Reformed. Koda, Alaafin Ọyọ gangan lo waa gbe Ọpa-aṣẹ fun wa, Baba wa Yẹmi Ẹlẹbuibọn gan-an wa nijokoo.

 

Iyẹn lo dẹ jẹ igba akọkọ ta a ri ọba ilẹ Yoruba to jẹ onipo kin-in-ni ( First class ọba) to maa lọ sibẹ lati gbe ọpa aṣẹ fun Aarẹ.

 

Ba a ṣe bẹrẹ OPC Reformed niyẹn ta a dẹ n ba a bọ latigba yẹn, Ọlọun dẹ n ba wa ṣe e, ẹyin oniroyin naa dẹ n ba wa ṣe e. Ẹ ṣe e gan-an, oju o ni i tiwa.

 

Awọn ipenija ta a koju ka too da OPC Reformed silẹ

 

Ipenija ko le ṣe ko ma si, ti mo ba yan an lai ṣalaye delẹ nikan ni. Ṣe ẹ mọ pe mo sọ ọ laarin kan, mo ni wọn gbe wa, wọn ti wa mọle, aimọye igbesẹ loriṣiiriṣii.

 

Ẹyin naa mọ pe ẹni tiru wa yii n koju nigba yẹn, bii igba ta a ba ni eera ati eerin jọ n du nnkan mọra wọn lọwọ ni, bẹẹ lo ṣe ri nigba yẹn. Ṣugbọn ẹni t’Ọlọrun ba n ṣe tiẹ, ko si nnkan to nawọ si ti ko ni i ṣee ṣe. Ati pe teeyan ba wa lori otitọ ati ododo, iru eeyan bẹẹ yẹn maa n ja ajaye ati ajaṣẹgun ni.

 

 Ootọ inu gangan lo gbe wa bori, ohun to jẹ ko tun rọrun ni pe teeyan ba ti mọ nnkan to n ṣe, to o dẹ nigbagbọ ninu ara ẹ ati ninu Ọlọrun, awọn kinni yẹn maa n jẹ keeyan tete debi to n lọ.

 

Ko si igbesẹ kan tabi iṣipopada kan teeyan ba fẹẹ ṣe, to ba tako eyi teeyan n ṣe lọwọ, to jẹ pe eeyan o ni i maa ṣiyemeji lori ẹ pe boya o maa jẹ tabi ko ni i jẹ.

 

Ṣugbọn ootọ inu ati alaye ọrọ leke, igba ti mo maa fi lọ yẹn, ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn ti n ronu bi mo ṣe n ronu, pe ọmọluabi la pe ara wa, tori nnkan ta a fẹẹ jẹ, a o gbọdọ fi ba nnkan ta a fẹẹ jẹ jẹ, a o gbọdọ ba ọjọ ọla wa jẹ, ao gbọdọ ta ọjọ ọla awọn ọmọ wa.

 

Ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ba mi ronu bẹẹ yẹn, wọn dẹ duro ti mi, wọn ni ki n niṣoo, ṣugbọn ko sowo, ko seeyan. Iyẹn lo fa a nigba yẹn to fi jẹ pe laarin kan, Agọ ọlọpaa Panti, ni Yaba, ranṣẹ pe wa, wọn ni ka wa,lori awọn ọrọ ti wọn sọ fun wọn nipa wa ni o.

 

A debẹ, ọtọ ni nnkan ta a gbe, ọtọ ni nnkan ti wọn ju, wọn gbe wa, wọn ti wa mọle, ṣugbọn awa naa ṣaa n sapa wa lọtun-un losi, iwọnba ọpọlọ ati ọgbọn t’Ọlọrun fun wa, a gbe lọọya dide,a ṣaa pada jade kuro ni Panti.

 

Lẹyin Panti naa, oriṣiiriṣii idunrunmọ, a n ko ibọn tira ẹni ti ki i ṣe kekere, ni ibudokọ Ikọtun ni, to jẹ pe awọn Area Commander Area M, n’Idimu Ikọtun, wọn duro sibẹ bayii, to jẹ pe wọn ti gẹgun de wa.

 

Awa fẹẹ ṣepade nibẹ lọjọ yẹn ni, awọn ti duro pe ta a ba ti de o, awọn maa pa ọta wa ni. Awa dẹ n ba tiwa lọ pe ka lọọ ṣepade ni. Emi o tiẹ ti i debẹ tawọn ọmọ mi ti n pe mi, ti wọn n sọ fun mi pe wahala ti n ṣẹlẹ o, awọn ọlọpaa wa nibẹ ti wọn n duro de mi o.

 

Igba ti mo maa debẹ, awọn ọlọpaa yẹn n ba mi sọrọ lọwọ, wọn lawọn naa ri ohun to wa nilẹ, awọn ti ribi ti ootọ wa, awọn ti ribi tawọn ọmọ ẹgbẹ fẹ. Wọn ni ṣugbọn awọn fẹẹ bẹ mi, ki n ma lọ si Olu ile.

 

Ibi ti wọn n pe ni Olu ile yẹn lati n ṣepade, Aarẹ wa oni yii lo ra ibẹ fun wa, wọn ra a fun OPC ni, orukọ OPC ni wọn fi ra ibẹ, to tumọ si pe gbogbo OPC lo lẹtọọ sibẹ. Emi n sọ nigba yẹn pe emi naa o ni i kuro nibẹ, mo ni ibẹ ni mo ti maa maa ṣepade ẹgbẹ temi naa.

 

A fẹẹ lọọ ṣepade, awọn ọlọpaa yẹn waa da wa duro, wọn ni ki n jọọ, pe ka ma lọ sibẹ yẹn, pe awọn maa wa aaye mi-in fun wa.

 

Emi ati ọlọpaa yẹn ṣi jọ n sọrọ lọwọ ni wọn ti n yinbọn bọ lọdọọ wa, emi dẹ n jẹ ko ye ọlọpaa yẹn, mo ni wọn n yinbọn bọ nibi yii o, mo ni ti wọn ba debi, emi o ni i kawọ sẹyin o, emi naa maa ṣe nnkan to yẹ k’emi naa ṣe gẹgẹ bii ọkunrin o.

 

Nigbẹyin ṣaa,  a da ẹgbẹ tiwa silẹ, a waa sọ ọ ni OPC, a wa fi Reformed yẹn sẹyin, ko ma baa da bii ROPC. Emi o ki n fẹ ki wọn maa sọ pe boya mo n ṣe nnkan kan mo n kọpi eeyan, ko ma da bii Reformed Ogboni Fraternity, mo ni ẹyin ni mo maa fi Reformed temi si, ba a ṣe fi Reformed yẹn sẹyin niyẹn.

 

Yatọ siyẹn, wọn le wa lọtun-un, le wa losi, awọn aa maa dunkooko mọ wa pe awọn maa pa wa, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe lonii yii, awa naa la ṣi n sọrọ yii.

 

Ọpọlọpọ awọn ti nnkan o ye nigba yẹn, nnkan ti ye awọn naa bayii. Ṣe ẹ mọ, nigba mi-in, nnkan teeyan fẹẹ jẹ ki i jẹ kẹlomi-in le ronu bo ṣe yẹ ko ronu, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oju kaluku ti la nisinyi. Ọrọ akọmọna wa niyẹn, ta a ba ti ni Ọmọ Oodua ni mi, to o ba ti ni tọkan-tọkan, ẹẹkeji, wa a ni oju ẹ ti la. Eeyan kankan o le muuyan kan lẹru mọ lori awọn nnkan to wa nilẹ yii.

 

Ipenija pọ loriṣiiriṣii, ṣugbọn mi o le maa sọ gbogbo ẹ naa lori afẹfẹ bẹẹ yẹn. A dupẹ pe ẹgbẹ n lọ bo ṣe yẹ ko lọ, awa naa la ṣi wa yii, ọmọ ẹgbẹ dẹ n le si i ni, a o pẹdin.

 

 

 

OPC Reformed ko ba awọn igun yooku ṣọta, a o si kere ninu aye, aṣiri wa gidi

 

 Ko si ẹgbẹ kankan ti emi o ba ni ajọṣepọ, nitori igbagbọ mi ni pe nnkan kan naa ni gbogbo wa jọ n ja fun, a kan maa n mu ojukokoro ati ọkanjua mọ nnkan ta a n  ṣe ni. K’Ọlọrun yọ iyẹn kuro lọrọ awa Yoruba lapapọ. 

 

Ẹgbẹ mi pẹlu ẹgbẹ Iba Gani Adams, ti nnkan ba da wa pọ, a jọ maa n ṣe e, ko si ẹgbẹ kankan ti mo ṣe lodi si, bo tilẹ jẹ pe laarin yẹn naa, igbesẹ yẹn, Gani Adams ati Baba Fasehun ni wọn jọ tẹle Jonathan lori idaaabo-bo ọpa epo nigba yẹn, to jẹ pe kinni yẹn bi oriṣiiriṣii silẹ ti ko dẹ yẹ ko ri bẹẹ.

 

Ṣe ẹ mọ, Gani ti wa laye ẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ ẹ, Baba Faṣehun naa dẹ wa, ọdọ Baba Faṣehun lemi dẹ wa, nnkan kan ko da wa pọ naa rẹpẹtẹ bẹẹ yẹn, ṣugbọn lẹyin igba yẹn, a ti pade lode ri ti wọn dẹ ti jọ pe awa mejeeji jade, pe ka ma jẹ ki wahala ṣẹlẹ, ka ṣe ara wa lọkan ki nnkan le dan mọọnran fun wa. 

 

Emi o ni nnkan kan ninu si ẹnikẹni, inu ara mi ni mo mọ, ṣugbọn lori ọrọ ilẹ Yoruba yii, ti mo ba lohun ti mo fẹẹ ṣe nibẹ, ma a lọ sibẹ, ti nnkan ba dẹ kan lọdọ temi naa, gbogbo wọn naa ni wọn n wa sọdọ mi, fun idi eyi, ajọṣepọ wa naa ni mo maa pe iru iyẹn.

 

Nipa jijẹ alagbara OPC taye mọ ẹgbẹ wa fun, nnkan ti OPC fi n jẹ OPC naa ni aṣiri.

 

Ti ko ba ti si aṣiri, ko si OPC. Tẹ ẹ ba ri OPC kan to sọ pe tohun ba kan, hmmm.

 

Ninu ẹgbẹ, a o fẹ iyẹn ku, Kristẹni wa ninu wa, Musulumi wa ninu wa, awọn ti wọn dẹ je pe Iṣẹṣe pọnbele ni wọn n ṣe, ti wọn o ṣe ẹsin kankan wa ninu wa. Ṣugbọn igbagbọ onikaluku lo maa n mu un lara da.

 

To o ba mọ pe Bibeli rẹ, to o ba ti ka Psalm 91, ti wọn ba n yinbọn bọ to o ba gbe e duro, wọn o ni i dọdọ ẹ, o lẹtọ ati lo o.

 

Bo dẹ jẹ Quran ẹ naa lo maa ni Fathia lo fẹẹ ka ti ibọn o ni dọdọ ẹ, o lẹtọọ ati lo o. Iwọ to o dẹ mọ pe nnkan mi-in wa to o fẹẹ lo, to o mọ pe ohun lo maa ṣiṣẹ to o maa fi lọ sibi to n lọ, to o maa fi bọ layọ, o lẹtọọ lati lo o.

 

Mo ranti igba ta a lọ sibi kan nikọja Ikorodu, ni 2016 naa kọ ni, nigba yẹn lawọn ọmọ kan paayan. Baalẹ ilu yẹn sọ pe o kere tan, pe wọn o paayan ninu ilu yẹn lọjọ kan, o ni wọn aa pa to eeyan mẹta, wọn n paayan niluu yẹn lojoojumọ ni.

 

Akoko yẹn ni awọn ajinigbe gbe ọba Oniba ana, ki i ṣe eyi to wa nibẹ nisinyi o, awọn ajinigbe kan wọ aafin wọn, wọn lọọ ji wọn gbe, igba yẹn ni.

 

Ti mo jade ti mo wọ ilu yẹn lọ nigba yẹn, ọkan ninu awọn akọroyin to wa nibẹ wa n sọ fun ọkan ninu awọn ọmọ mi pe ọga yin yii, boun ṣe n wo o yii, o de da bii pe ina n jade loju ẹ.

 

Mo wa n jẹ ko ye iyẹn pe ko ma da wọn lohun, ẹni ti wọn maa maa gbe lẹnu jo ni wọn n wa, Ọlọrun naa ṣaa ni ka maa kepe.

 

Pataki ibẹ julọ ni pe, nnkan ta a gbe dani yii, ko ṣee fi oju lasan ṣe, ko dẹ ṣee fi gbẹrẹ ṣe, afi teeyan ba fẹẹ da ẹmi ara ẹ legbodo lo ku, k’Ọlọrun ma dẹ da ẹmi wa legbodo.

 

Nnkan ta a maa ṣe, Ọlọrun ti fi han wa, iwọ to o ba wa ni o ṣe nnkan yẹn, to o dẹ fẹẹ gbe nnkan ta a gbe dani yii dani, tọọ, Ọlọrun aa tubọ maa da aabo bo gbogbo wa ṣaa.

 

Lọrọ kan, aṣiri wa sibẹ ti ko kuro nibẹ. Aṣiri yẹn o dẹ le kuro nibẹ titi laelae. A faaye gba ẹsin, ko si ẹsin teeyan n ṣe ti ko si ninu ẹgbẹ, bi mo ṣe sọ, Kristẹni wa nibẹ,  Musulumi wa nibẹ,awọn Oniṣẹṣe dẹ wa nibẹ, gbogbo ẹ lo wa ninu ẹgbẹ, ohun ti kaluku dẹ n ṣe ko di nnkan ta a n ṣe ninu ẹgbẹ lọwọ.

 

 Ta a ba n ṣe nnkan ta a n ṣe yii, a maa n pe awọn aafaa nigba mi-in pe ki wọn ṣadua fun wa, aa maa pe awọn Kristẹni naa, awọn wolii, ki wọn ṣadua fun wa nigba mi-in. To ba dẹ di igba ti Iṣẹṣe naa, a maa ṣe e, bo ṣe ri niyẹn, gbogbo ẹ lo wa ninu ẹgbẹ.    

 

 

 

Ọrọ owo ti Jonathan gbe fun Gani Adams ko kan mi, owo Gani ko si lọdọ temi o

 

Ṣe ẹ mọ pe mo sọ ọ lati ibẹrẹ pe emi ni Akọwe agba fun Baba Faṣehun, owo ti Jonathan ba gbe fun Gani Adams atawọn ọmọ ẹgbẹ ẹ ko kan mi, mi o dẹ lẹtọọ lati lọọ yọju sibẹ, emi o dẹ ki n da si nnkan ti ko kan mi, iyẹn o kan mi, ko ra mi rara.

 

Ṣugbọn eyi to kan mi ni ti ọrọ Ọmọwe Faṣehun ati ọrọ ilẹẹ Yoruba. Nnkan to ṣẹlẹ nisinyi, ka ni emi loju kokoro owo ni, ẹ jẹ n ṣalaye kinni yii.

 

Ṣe ẹ ri i, ko ye ọpọlọpọ eeyan bi kinni yii ṣe bẹre gangan. Igba ti ọrọ iṣẹ ṣiṣọ ọpa epo yẹn maa bẹrẹ gangan, Ikọtun lo ti bẹrẹ.

 

O ni ọlọpaa kan to jẹ ọrẹ wa to maa n wa sọdọ wa, awa ni ẹkun kan (zone) lagbegbe yẹn, ibi ti zone yẹn wa jẹ adugbo ti ọpa epo gba kọja, o wa pe wa lọjọ kan pe ṣe wọn n fun wa lowo la fi duro nibi ta a wa yii ni, awa ni owo bawo, ko sẹni to n fun wa lowo o, a sọ fun un pe a o fẹ ki aṣemaṣe wa nibi ta a ba wa la ṣe n wa nibẹ. O wa ni kinni yẹn, owo buruku ni o, pe o le di owo fun wa.

 

Ọgbẹni ọlọpaa yẹn lawa wa ba sọrọ pe to ba jẹ pe loootọ ni kinni naa le di owo fun wa, ko ma jẹ ko jẹ pe adugbo wa n’Ikọtun nikan lo ti maa di owo, pe ka kuku ṣe e ki gbogbo ẹgbẹ jẹ anfaani ẹ. La fi mu ọlọpaa yẹn lọọ ba Ọmọwe Faṣehun nijọ kin-in-ni ana, emi, maanu kan, Alaaji Taofik to jẹ National Organizing Secretary, Alaaji Muda to jẹ Monitoring Commander nigba yẹn, pẹlu Ṣọla Edward to jẹ P.R.O la ṣaa jọ jokoo ta a ṣagbatẹru ẹ.

 

Nigba to di asiko kan, Alaaji Muda yẹn o yọju mọ, o ku awa mẹta. Gbogbo eto pata ti wọn ṣe lori ọrọ iṣẹ yẹn, awa la ṣe gbogbo ẹ pẹlu Baba Faṣehun. Ẹyin-o-rẹyin to di aarin kan, ṣe ẹ mọ pe ọrọ Naijiria, jẹ ki n jẹ ni wọn fi n ṣe. Igba to di aarin kan lawọn kan sọ pe awọn  o le wojuu Baba lori iṣẹ yẹn, ni wọn fi gbe Gani Adams wọle.

 

Gani o mọ biṣẹ yẹn ṣe jẹ, Baba dẹ pe oun naa wọle pe bo ba ṣe jẹ, ko kuku je pe  gbogbo OPC ilẹẹ Yoruba lo maa maa ṣe kinni yẹn.

 

 Igba to wa ti n di pe ọrọ ti Ọṣinbajo wa jẹ jade, ti wọn sọ fun wọn pe ohun ti wọn fẹẹ gbe wa yii, a gbọdọ fi ṣiṣẹ fun ẹgbe wọn ni o, kawọn le di aarẹ o, to dẹ jẹ awa naa la n sọ latijọ yii pe wọn n fiya jẹ Yoruba, Yoruba o nipo kankan ninu ijọba, ki la le ṣe ka fi ni ilọsiwaju, ti Ọṣinbajo dẹ jade gẹgẹ bii Igbakeji, iyẹn lawa fi wo o pe to ba jẹ nitori nnkan ta a fẹẹ jẹ ni, awa o ni i ba yin ṣe e.

 

 O daa ka kuku tẹle ọmọ Yoruba tiwa, ka dẹ nigbagbọ pe to ba debẹ, bo tiẹ jẹ pe a ri i bo ṣe ri naa, pe to ba debẹ, ayipada aa le de ba gbogbo ọmọ Yoruba lapapọ, ohun ti awa duro le lori niyẹn, ibura ta a bu niyẹn, pe Yoruba lo maa ṣiwaju ninu gbogbo nnkan ta a ba n ṣe. Ki i ṣe ọrọ pe boya kinni.

 

Ka ni nigba yẹn, emi yii gba ni atawọn to ku,pe owo lo delẹ yii, ẹ jẹ ka lọọ pin owo, a maa gbowo gidi lọwọ baba nao, a maa gbadun, a maa ṣe nnkan ta a fẹẹ ṣe.

 

Emi ni akọwe nao, igba yẹn dẹ ree, ẹni to jẹ Igbakeji ti ṣalaisi, emi ni mo da bii Igbakeji Baba. Ẹni to jẹ National Organizing ni amugbalẹgbẹẹ, ẹni to jẹ ikẹta ni P.R.O. Awa ta a di ẹgbẹ mu nigba yẹn niyẹn ti wọn ba n sọ pe ẹgbẹ Faṣehun, ni gbogbo igba yẹn, ki wọn lọọ beere lọwọ ẹnibọdi, awa ta n jẹ bẹ leleyii.

 

 

 

Gbogbo ipinlẹ kaakiri, ti Ọmọwe Faṣehun ta a lẹgbẹ si, awa ta a lọọ fẹgbẹ ọhun lelẹ fun wọn ree. Baba ti dagba, irin meloo ni baba fẹẹ rin.

 

Bi mo ṣe n sọ lọ, ọmọluabi la maa n pera wa nilẹẹ Yoruba, mi o dẹ ki n fẹ ko jẹ pe wa a ti sọ pe o fẹẹ ṣe nnkan, oo wa ni i ṣe e mọ. Ohun lo da bii ọrọ Ikorodu ti mo n sọ lọ lẹẹkan yẹn, mo fun awọn eeyan yẹn ni gbedeke ọjọ mẹrinla, pe ti wọn o ba dawọ nnkan ti wọn n ṣe ninu ilu yẹn duro, pe mo maa wọnu ilu yẹn, mo n bọ waa ba wọn, pe a maa fopin si i.

 

Ẹ o le wa silẹẹ Yoruba kẹ ẹ maa jiiyan gbe, kẹ ẹ maa paayan kẹ ẹ maa ṣe oriṣiiriṣi. Ọjọ to pe ọjọ kẹrinla gẹlẹ, mo wọnu ilu yẹn lọ taara ni.

 

Igba ti mo denu ilu yẹn,Kabiyesi yẹn bi mi pe ṣe mo nilẹ niluu awọn ni, o ni nitori lọjọ ti wahala naa ti n ṣẹlẹ, awọn o ri eeyan kankan to dide waa gbeja awọn. Mo ni mi o nilẹ nibẹ, ṣugbọn tori pe ọmọ Yoruba ni mi, tiya ba ti n jẹ ọmọ Yoruba, gbogbo ẹgbẹ wa lo ti n jẹ niyẹn, nitori naa, a jọ maa dide jija yẹn ni.

 

Igba ta a wọnu ilu yẹn, Amosun ni gomina nigba yẹn, lo pe, lo ni ki Kabiyesi ba wa sọrọ o, ko ma jẹ ki wọn da wahala silẹ o. Ṣugbọn  a dupẹ lọwọ Ọlọrun, ọjọ keji ta a kuro nibẹ ni awọn ọlọpaa, awọn ṣọja wọnu ilu yẹn ti wọn jẹ kalaafia jọba nibẹ.

 

Irin ta a rin lọjọ yẹn ni awọn ti wọn ji Kabiyesi Oniba ana ri, ni wọn fi fi wọn silẹ, wọn ni wọn sọ fawọn pe, ṣe nitori tawọn lawa fi jade.

 

Gbogbo owo ti wọn n beere, wọn o rowo kankan gba mọ. Kabiyesi ni wọn fi awọn sinu ọkọ, wọn waa ti awọn nikan pẹlu ọkọ ẹyọkan pe kawọn maa lọ, awọn maa ri ilu, wọn ni bawọn ṣe wa ọkọ tawọn fi deluu funra awọn niyẹn.

 

Igbesẹ ta a gbe nigba yẹn, nitori a ti sọ pe a  maa gbe e ni, emi o dẹ ki n sọrọ ki n ma ṣe bẹẹ, mo yatọ sawọn to maa sọ pe a maa pa igba, a maa pa awo, a maa debi kan, a maa lọ Aso Rock, irọ.

 

Afi ti mi o ba sọ ọ, ti mo ba ti sọ ọ, ‘action’ maa tẹle e bẹẹ ni. Nnkan to ṣẹlẹ niyẹn, ipinnu mi, nnkan ti mo ba Ọlọrun sọ pe iya o ni i jẹ Yoruba, to ba jẹ pe nnkan ti mo le ṣe nikapa mi lati dawọ iya yẹn duro, iya yẹn o ni i jẹ ọmọ Yoruba yẹn o.

 

Nnkan ta a ro niyẹn lori ọrọ yii, owo fun ni o to eeyan, owo maa tan nao, ki lowo.

 

Gbogbo awọn ti wọn ṣe kinni yẹn nigba yẹn naa nisinyi, ta a ba wọn sọ ti wọn o gbọ, ti wọn ro pe nitori owo wa nibẹ, awọn maa rowo, lopin gbogbo ẹ naa, ẹ beere pe elo ni wọn ri.

 

Ọtọ niye ti wọn n reti, ọtọ niye ti wọn fun wọn. Ati ju wa ni wọn ba lọ, aito ni wọn ba bọ, ọpọlọpọ wọn lo n kabaamọ, pe ka ni awọn tiẹ ti mọ ni, kawọn ma gbọ nnkan tawọn eeyan yẹn sọ fawọn.

 

Owo maa tan,nnkan ta a bura le lori ni kẹ ẹ jẹ ka maa duro le lori ka dẹ maa tẹle, bi aarin yẹn ṣe ri niyẹn o, ki i ṣe lori ọrọ olowode o. Owo Gani ko si lọdọ temi o.   

 

 

 

Walahi, bi mo wa nibi t’Ọbasanjọ ti paṣẹ fawọn ọba Ọyọ ni, wọn o ni i dide

 

Ṣe ẹ ri iṣẹlẹ yẹn, o jẹ nnkan to dun mi gidi gan-an, idi to dẹ fi dun mi ni pe mi o ni oore ọfẹ ati wa ninu apejọ yẹn, nitori ọmọ ilu yẹn gangan ni mi, ọmọ Iṣẹyin ni mi.

 

Walahi, ka ni mo wa nibẹ, awọn ọba yẹn o ni i dide. Mo maa n sọ ọ daadaa ti mo ba lọ sode, ti mo ba ri aṣoju ijọba yoowu nibẹ ti mo dẹ tun ri ọba nibẹ, ma a kọkọ ki ọba ki n too ki aṣoju ijọba yẹn. Nitori ọdun eegun lọrọ wọn, ọdun maa tan ni, ṣugbọn awọn ọba wa nibẹ kanrin-kese ni.

 

Owe ti Yoruba maa n pa, pe b’ọba kan o ku, omi-in ki i jẹ, awọn oloṣelu yii naa lo gbe e de pe bọba kan o ku omi-in le jẹ, nibi ọwọ agbara ti wọn n lo.

 

Iwe ofin ilẹ wa ti wọn dẹ n lo lori ọrọ ọlọbade lo fa a. Kinni yẹn jẹ nnkan to gba riro, o yẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba maa sunkun ni, ṣugbọn ṣe ẹ mọ pe ọna irori kaluku wa yatọ, ọna ti kaluku maa n gba ro nnkan yatọ sira wọn.

 

Ẹlomi-in aa kan ronu pe ẹn, awọn ọba yẹn naa, ṣebi nnkan toju wọn wa lojuu wọn ri, ọba meloo ni wọn fi Ifa mu mọ, ṣebi ọna ẹburu ni ọpọlọpọ ninu wọn gba ti wọn fi debi ọba ti wọn de yẹn.

 

Wọn aa ni nnkan toju wọn wa lojuu wọn ri o, ko kan awọn.

 

Ṣugbọn mo fẹ sọ fawọn to ba ni iru ero bẹẹ, pe ko si bo ṣe le wu ko ri, Yoruba naa ni wọn ṣi maa maa pe wọn. Fun idi eyi, a maa kọkọ le akata lọ na, ka too waa fabọ ba adiẹ ni, la ṣee gbọdọ maa ṣọ iru awọn ọrọ bẹẹ yẹn.

 

 Labẹ ẹtọ, ọba ba lori ohun gbogbo, awọn ọba ati gbogbo Yoruba gbọdọ ja ija lori ba a ṣe maa pada si bi wọn ṣe n yan ọba gangan, to jẹ pe ẹni ti Ifa rẹ ba pọ ju lo maa n jọba, ti wọn o ni i figba kan bọ ọkan ninu mọ.

 

Iru nnkan to ṣẹlẹ nijọ yẹn bayii, awọn ọba yẹn naa, wọn o jẹwọọ pe ọba lawọn, o yẹ ki wọn jẹwọọ pe ọba lawọn ni.

 

 Ẹ maa ri i pe tẹ ẹ ba wo kinni yẹn lọjọ yẹn, mo wo o mo dẹ n tun un wo, awọn kọọkan tun n rẹrin-in ninu wọn. Mo waa wo o pe haa, nitori nnkan ti wọn fẹẹ jẹ, wọn dẹ... (Aarẹ  dakẹ) haa, gbogbo Yoruba ni wọn n ta!

 

Gbogbo Yoruba patapata ni wọn ta, ki i ṣe ara wọn ni wọn ta, omi-in tun n rẹrin-in ninu wọn, ọrọ to jẹ o yẹ ki oju gbogbo wọn le ni, ṣe o fẹ na wọn ni?  Ko le na wọn! Ṣugbọn ẹru o jẹ.

 

 Ka ni lọjọ yẹn, wọn pe ara wọn jọ pe awa ni maanu yii dọti bayii, nitori Ọlọrun, ki la le ṣe fun un, kawọn naa pe bíríkótó, ki wọn pe bìrìkòtò, ki wọn dẹ jẹ ki nnkan kan ṣẹlẹ ko dẹ mọ pe ọdọ wọn ni nnkan yẹn ti wa.  Ẹlomi-in o ni i dan iru ẹ wo mọ, ṣugbọn nitori pe awọn naa kan wo o, wọn dẹ fi ṣe osun, wọn fi n para, wọn ti gbagbọ pe awọn ko ni onigbeja, nitori awọn naa ko mu un bo ṣe yẹ ki wọn mu un mọ.

 

Ọba mi-in aa ni oun ki i ṣe ọba Oniṣẹṣe.    

 

Ṣe ẹ wa ri ti awọn ti wọn n sọ pe ijọba ju ọba lọ labẹ ofin Naijiria, mo ti sọ ọ siwaju pe ọna ti kaluku n gba ronu,ọtọọtọ ni.

 

Ẹni to sọ bẹẹ naa ri i sọ, nitori tẹ ẹ ba wo ofin Naijiria, o ti fi awọn ọba sabẹ ijọba.

 

Ko too di pe awọn oyinbo amunisin, awọn oyinbo waa mu wa lẹru, bawo la ṣe n ṣejọba ara wa? Ṣebi awọn ọba lo n ṣejọba fun wa. Mo ti sọ ọ siwaju, mo lo yẹ ka ja lori ofin to fi ọba si abẹ awọn oloṣelu.

 

Ọba funra ẹ naa dẹ tun le ja funra ẹ to ba loun o fẹ, ma foko mi ṣọna, ọjọ kan leeyan n kọ ọ. T’ọba ba dide to loun o fẹ nnkan kan latọdọ yin, ẹ fi mi silẹ, mi o nilo ọpa aṣẹ latọdọ yin, ẹ ṣe maa gbe ọpa aṣẹ fun mi,awọn oloye afọbajẹ wa nao, awọn ni ki wọn gbe ọpa áṣẹ fun mi, ko dẹ duro lori ẹsẹ rẹ.

 

To ba kọ kinni yẹn fun wọn, toun ba ri i ṣe, omi-in naa maa ri i ṣe. Ọba meloo lo le ṣeru nnkan yẹn, idi ati itumọ rẹ naa si ni pe ọba mi-in gan, ọba ko tọ si i, awọn oloṣelu yii naa lo lọọ ba, pe ẹ jọọ, ẹ ti mi lẹyin, ti mo ba debẹ, ma a ṣe’fẹ yin. Ṣe iru ọba bẹẹ yẹn, to ba waa debẹ, ki lẹ ro pe o maa ṣe?   

 

Ẹyin naa e wo igba ti awọn oyinbo n ṣelu pẹlu ti ọlọbade ta a n ṣe lọwọ nisinyi.

 

Ṣe a ni ọba ni igberiko kiri nigba yẹn, ọba gan-an ti pọju bayii, nnkan to fa ti ko ṣe fẹẹ niyi loju awọn ijọba yẹn mọ niyẹn.

 

Ka ni ọba mọ niwọn bo ṣe ri nigba yẹn lọhun-un ni, ti ki i ṣe pe adugbo kan, ọba kan, adugbo ibẹ yẹn,ọba mi-in wa nibẹ,ẹnu ọba gan-an aa tolẹ, ẹnu ọba aa de ka ilu, nitori ẹni ti wọn fẹẹ fi jọba, to jẹ Iṣẹṣe lo mu un to dẹ ṣe oro ile fun un to pe, gbogbo ilu aa duro ti i, nnkan to dẹ maa fi jẹ ọba yẹn, wọn aa pese ẹ fun un.

 

 Ṣugbọn to ba ti lọọ n ba oloṣelu, hmmm.

 

Fun idi eyi, kinni yẹn, igbaju lojuu gbogbo ọmọ Yoruba ni, oun lo fi jẹ pe awọn eeyan maa n sọ ọ nigba mi-in pe Baba Ọbasanjọ ki i ṣe Yoruba, pe ka ni wọn jẹ Yoruba ni, awọn igbesẹ kọọkan ti wọn maa n gbe, wọn o ni i gbe e.

 

Ẹ wo igba ibo Awolọwọ, Ọbasanjọ wa nibẹ, iyẹn lọ bẹẹ yẹn. Ẹ wo igba ti MKO Abiọla naa,igba ti Ọbasanjọ ṣẹṣẹ waa kuro nibẹ, ti Buhari, Hausa debẹ lo ṣẹṣẹ waa ranti Abiọla, to waa fi iyi rẹ fun un, nnkan to yẹ kẹyin ṣe.

 

Ẹ sọ nnkan ti baba yii ṣe!

 

Ọrọ yii n dun mi gan-an, ka ni mo wa nibẹ lọjọ yẹn sẹẹ, awọn ọba yẹn o ni i dide, nnkan to ba maa ṣẹlẹ lo maa ṣẹlẹ, nitori ma a jẹ ko ye wọn pe laye, ẹ o le maa dọtii Yoruba, aṣeju yin ti n pọju.

 

 Ẹ wo idibo to lọ yii naa, ṣe wọn duro ti Aarẹ to wa nibẹ lọwọlọwọ yii? Ṣebi ọtọ lẹni ti wọn ti lẹyin. Gbogbo nnkan to ba ti jẹ mọ Yoruba, ko yẹ ki wọn maa pe wọn sibẹ mọ. Nnkan to yẹ ki gbogbo awa Yoruba ṣe nisinyi ni pe, ode eyikeyi to ba jẹ ti Yoruba, wọn o fẹẹ ri wọn nibẹ, nitori wọn o ṣojuu wa.

 

Ṣugbọn ẹnu o ko, bẹnikan ba loun fẹẹ ṣe e, awọn kan aa gba ẹyin, wọn aa tun lọọ sọ aṣiri yẹn fun wọn pe awọn fẹẹ ṣẹ nnkan bayii, awọn kan aa tun ni awọn o ba yin ṣe e o, awọn o ba yin si ninu ẹ o, nitori awọn nnkan ti wọn maa jẹ ti ko jẹ ki wọn gbọn, wọn le ro pe awọn le ri awọn anfaani kan jẹ, nnkan to dẹ n fa ọwọ aago wa sẹyin nilẹẹ Yoruba niyẹn.

 

Gbogbo wa gbọdọ dide, ka fẹnuko pe gbogbo ode to ba jẹ mọ ti Yoruba, ẹ ma pe baba yii sibẹ mọ.

 

No comments:

Post a Comment

Pages